ÌWÉ ÒWE 5:7-14

ÌWÉ ÒWE 5:7-14 YCE

Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ẹ má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu. Ẹ jìnnà sí alágbèrè obinrin, kí ẹ má tilẹ̀ súnmọ́ ẹnu ọ̀nà rẹ̀, kí ẹ má baà gbé ògo yín fún ẹlòmíràn, kí ẹ sì fi ìgbé ayé yín lé aláìláàánú lọ́wọ́. Kí àjèjì má baà jèrè iṣẹ́ yín, kí làálàá rẹ má sì bọ́ sápò àlejò. Kí o má baà kérora nígbẹ̀yìn ayé rẹ, nígbà tí o bá di ìjẹ fún ẹni ẹlẹ́ni nígbà náà ni o óo wí pé, “Kí ló dé tí mo kórìíra ìtọ́ni, tí ọkàn mi sì kẹ́gàn ìbáwí! N kò fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn olùkọ́ mi n kò sì gba ti àwọn tí wọn ń tọ́ mi sọ́nà. Èyí ni ó sún mi dé etí bèbè ìparun, láàrin àwùjọ eniyan.”