Owe 5:7-14
Owe 5:7-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ gbọ́ temi nisisiyi, ẹnyin ọmọ, ki ẹnyin ki o máṣe yà kuro li ọ̀rọ ẹnu mi. Takete kuro lọdọ rẹ̀, má si ṣe sunmọ eti ilẹkun ile rẹ̀: Ki iwọ ki o má ba fi ọlá rẹ fun ẹlomiran, ati ọdun rẹ fun ẹni-ìka; Ki a má ba fi ọrọ̀ rẹ fun ajeji enia; ki ère-iṣẹ ọwọ rẹ ki o má ba wà ni ile alejo. Iwọ a si ma kãnu ni ikẹhin rẹ̀, nigbati ẹran-ara ati ara rẹ ba parun. Iwọ a si wipe, emi ha ti korira ẹkọ́ to, ti aiya mi si gàn ìbawi: Ti emi kò gbà ohùn awọn olukọ́ mi gbọ́, tabi ki emi dẹti mi silẹ si awọn ti nkọ́ mi. Emi fẹrẹ wà ninu ibi patapata larin awujọ, ati ni ijọ.

Owe 5:7-14 Yoruba Bible (YCE)
Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ẹ má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu. Ẹ jìnnà sí alágbèrè obinrin, kí ẹ má tilẹ̀ súnmọ́ ẹnu ọ̀nà rẹ̀, kí ẹ má baà gbé ògo yín fún ẹlòmíràn, kí ẹ sì fi ìgbé ayé yín lé aláìláàánú lọ́wọ́. Kí àjèjì má baà jèrè iṣẹ́ yín, kí làálàá rẹ má sì bọ́ sápò àlejò. Kí o má baà kérora nígbẹ̀yìn ayé rẹ, nígbà tí o bá di ìjẹ fún ẹni ẹlẹ́ni nígbà náà ni o óo wí pé, “Kí ló dé tí mo kórìíra ìtọ́ni, tí ọkàn mi sì kẹ́gàn ìbáwí! N kò fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn olùkọ́ mi n kò sì gba ti àwọn tí wọn ń tọ́ mi sọ́nà. Èyí ni ó sún mi dé etí bèbè ìparun, láàrin àwùjọ eniyan.”
Owe 5:7-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ dẹtí sí mi, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe yàgò kúrò nínú ọ̀rọ̀ tí mo sọ. Rìn ní ọ̀nà tí ó jìnnà sí ti rẹ̀, má ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀ Àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo ọlá rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́ àti ọjọ́ ayé rẹ fún ìkà ènìyàn. Kí a má ba à fi ọrọ̀ rẹ fún àjèjì ènìyàn, kí làálàá rẹ sì sọ ilé ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀. Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora, nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó! Ọkàn mi ṣe wá kórìíra ìbáwí! N kò gbọ́rọ̀ sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu, tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́. Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátápátá ní àárín gbogbo àwùjọ ènìyàn.”