Owe 31

31
Ìmọ̀ràn fún Ọba
1Ọ̀RỌ Lemueli, ọba, ọ̀rọ-ẹkọ́ ti ìya rẹ̀ kọ́ ọ.
2Kini, ọmọ mi? ki si ni, ọmọ inu mi? ati kini, ọmọ ẹ̀jẹ́ mi?
3Máṣe fi agbara rẹ fun awọn obinrin, tabi ìwa rẹ fun awọn obinrin ti mbà awọn ọba jẹ.
4Kì iṣe fun awọn ọba, Lemueli, kì iṣe fun awọn ọba lati mu ọti-waini; bẹ̃ni kì iṣe fun awọn ọmọ alade lati fẹ ọti lile:
5Ki nwọn ki o má ba mu, nwọn a si gbagbe ofin, nwọn a si yi idajọ awọn olupọnju.
6Fi ọti lile fun ẹniti o mura tan lati ṣegbe, ati ọti-waini fun awọn oninu bibajẹ.
7Jẹ ki o mu, ki o si gbagbe aini rẹ̀, ki o má si ranti òṣi rẹ̀ mọ́.
8Yà ẹnu rẹ fun ayadi, ninu ọ̀ran gbogbo ẹniti iṣe ọmọ iparun.
9Yà ẹnu rẹ, fi ododo ṣe idajọ, ki o si gbèja talaka ati alaini.
Iyawo tí Ó Ní Ìwà Rere
10Tani yio ri obinrin oniwà rere? nitoriti iye rẹ̀ kọja iyùn.
11Aiya ọkọ rẹ̀ gbẹkẹle e laibẹ̀ru, bẹ̃ni on kì yio ṣe alaini ère iṣẹ.
12Rere li obinrin na yio ma ṣe fun u, kì iṣe buburu li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo.
13Obinrin na yio ma ṣafẹri kubusu ati ọ̀gbọ, o si fi ọwọ rẹ̀ ṣiṣẹ tinutinu.
14O dabi ọkọ̀ oniṣowo: o si mu onjẹ rẹ̀ lati ọ̀na jijin rére wá.
15On a si dide nigbati ilẹ kò ti imọ́, a si fi onjẹ fun enia ile rẹ̀, ati iṣẹ õjọ fun awọn ọmọbinrin rẹ̀.
16O kiyesi oko, o si mu u: ère ọwọ rẹ̀ li o fi gbin ọgbà-ajara.
17O fi agbara gbá ẹ̀gbẹ rẹ̀ li ọjá, o si mu apa rẹ̀ mejeji le.
18O kiyesi i pe ọjà on dara: fitila rẹ̀ kò kú li oru.
19O fi ọwọ rẹ̀ le kẹkẹ́-owú, ọwọ rẹ̀ si di ìranwu mu.
20O nà ọwọ rẹ̀ si talaka; nitõtọ, ọwọ rẹ̀ si kàn alaini.
21On kò si bẹ̀ru òjo-didì fun awọn ara ile rẹ̀; nitoripe gbogbo awọn ara ile rẹ̀ li a wọ̀ li aṣọ iṣẹpo meji.
22On si wun aṣọ titẹ́ fun ara rẹ̀; ẹ̀wu daradara ati elese aluko li aṣọ rẹ̀.
23A mọ̀ ọkọ rẹ̀ li ẹnu-bode, nigbati o ba joko pẹlu awọn àgba ilẹ na.
24O da aṣọ ọ̀gbọ daradara, o si tà a, pẹlupẹlu o fi ọjá amure fun oniṣòwo tà.
25Agbara ati iyìn li aṣọ rẹ̀; on o si yọ̀ si ọjọ ti mbọ.
26O fi ọgbọ́n yà ẹnu rẹ̀; ati li ahọn rẹ̀ li ofin iṣeun.
27O fi oju silẹ wò ìwa awọn ara ile rẹ̀, kò si jẹ onjẹ imẹlẹ.
28Awọn ọmọ rẹ̀ dide, nwọn si pè e li alabukúnfun, ati bãle rẹ̀ pẹlu, on si fi iyìn fun u.
29Ọpọlọpọ awọn ọmọbinrin li o hùwa rere, ṣugbọn iwọ ta gbogbo wọn yọ.
30Oju daradara li ẹ̀tan, ẹwà si jasi asan: ṣugbọn obinrin ti o bẹ̀ru Oluwa, on ni ki a fi iyìn fun.
31Fi fun u ninu eso-iṣẹ ọwọ rẹ̀; jẹ ki iṣẹ ọwọ ara rẹ̀ ki o si yìn i li ẹnu-bodè.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Owe 31: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa