Oni Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé yìí jẹ́ àkójọpọ̀ èrò ọ̀jọ̀gbọ́n kan ẹni tí ó ṣe ìjìnlẹ̀ ìtọ́kasí bí ẹ̀mí eniyan ṣe kúrú tó, ati bí ìgbòkègbodò ṣe kún ìgbé-ayé ẹ̀dá. Ó mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ pẹlu àwọn ìdájọ́ tí kò tọ̀nà tí ó sì rúni lójú ati airojutuu ayé ẹni. Èyí ni ó mú kí ó sọ pé “asán ni ìgbé-ayé.” Kò yé e bí Ọlọrun ti ń darí àyànmọ́ ẹ̀dá. Sibẹ ó rọ àwọn eniyan láti ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n sì gbádùn àwọn ẹ̀bùn Ọlọrun tẹ́rùn.
Ọ̀pọ̀ ninu àwọn èrò ọ̀jọ̀gbọ́n náà ni ó dà bí ẹni pé kò ṣàǹfààní fúnni, tí ó sì ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn, ṣugbọn nítorí pé irú ìwé yìí wà ninu Bibeli, ó fi hàn pé igbagbọ inú Bibeli fẹjú, ó sì fi ààyè sílẹ̀ fún ainigbagbọ ati ẹ̀mí iyèméjì. Ọpọlọpọ àwọn tí ó jẹ́ pé nípa fífi ojú Ìwé Oníwàásù wo ọ̀rọ̀ ìgbé-ayé wọn ni wọ́n ṣe máa ń ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Ṣugbọn wọ́n tún rí i pé Bibeli kan náà tí ó sọ nípa ainitumọ ìgbé-ayé gẹ́gẹ́ bí èrò ọkàn wọn, ni ó tún fún wọn ní ìrètí nípa Ọlọrun, tí ó fún ìgbé ayé ní ìtumọ̀, tí ó ga ju èyí tí àwa ẹ̀dá mọ̀ lọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Oni Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa