Owe 17:19-21

Owe 17:19-21 YBCV

Ẹniti o fẹ ìja, o fẹ ẹ̀ṣẹ; ẹniti o kọ́ ẹnu-ọ̀na rẹ̀ ga, o nwá iparun. Ẹniti o ni ayidayida ọkàn kì yio ri ire: ati ẹniti o ni ahọn ọ̀rọ-meji, a bọ sinu ibi. Ẹniti o bi aṣiwère, o bi i si ibinujẹ rẹ̀; baba aṣiwère kò si li ayọ̀.