Owe 17:1-14

Owe 17:1-14 YBCV

OKELE gbigbẹ, ti on ti alafia, o san jù ile ti o kún fun ẹran-pipa ti on ti ìja. Ọlọgbọ́n iranṣẹ yio ṣe olori ọmọ ti nhùwa itiju, yio si pin ogún lãrin awọn arakunrin. Koro ni fun fadaka, ati ileru fun wura: bẹ̃li Oluwa ndan aiya wò. Oluṣe buburu fetisi ète eke; ẹni-eké a si ma kiyesi ọ̀rọ ahọn buburu. Ẹnikẹni ti o ba sín olupọnju jẹ, o gàn Ẹlẹda rẹ̀: ẹniti o ba si nyọ̀ si wahala kì yio wà li aijiya. Ọmọ ọmọ li ade arugbo: ogo awọn ọmọ si ni baba wọn. Ọ̀rọ daradara kò yẹ fun aṣiwère; bẹ̃li ète eke kò yẹ fun ọmọ-alade. Okuta iyebiye jẹ ẹ̀bun li oju ẹniti o ni i; nibikibi ti o yi si, a ṣe rere. Ẹniti o bò ẹ̀ṣẹ mọlẹ, o nwá ifẹ; ṣugbọn ẹniti o tun ọ̀ran hú silẹ, o yà ọrẹ́ nipa. Ibawi wọ̀ inu ọlọgbọ́n jù ọgọrun paṣan lọ ninu aṣiwère. Ẹni-ọ̀tẹ a ma wá kiki ibi kiri; nitorina iranṣẹ ìka li a o ran si i. O yá ki ẹranko beari ti a kó li ọmọ ki o pade enia, jù aṣiwère lọ ninu wère rẹ̀. Ẹnikẹni ti o ba fi ibi san ire, ibi kì yio kuro ninu ile rẹ̀. Ẹniti o daju fun omi dabi olupilẹṣẹ ìja; nitorina fi ìja silẹ ki o to di nla.