Òwe 17:1-14

Òwe 17:1-14 YCB

Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ sàn ju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà. Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ, yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ. Iná ni a fi fọ́ Fàdákà àti wúrà Ṣùgbọ́n OLúWA ló ń dán ọkàn wò. Ènìyàn búburú ń tẹ́tí sí ètè tí ń sọ ibi òpùrọ́ a máa fetí sí ahọ́n búburú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sín olùpọ́njú jẹ, ó gan Ẹlẹ́dàá rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ń yọ̀ sí ìyọnu kò ní lọ láìjìyà. Ọmọ ọmọ ni adé orí arúgbó ògo àwọn ọmọ sì ni òbí jẹ. Ọ̀rọ̀ dídùn kò yẹ aṣiwèrè, bẹ́ẹ̀ ni ètè èké kò yẹ ọmọ-aládé! Òkúta iyebíye jẹ́ ẹ̀bùn ní ojú ẹni tí ó ni í, ibikíbi tí ó yí sí, á ṣe rere. Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì ní yà. Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun olóye ènìyàn ju ọgọ́rùn-ún pàṣán lọ lẹ́yìn òmùgọ̀. Orí kunkun ni ènìyàn ìkà máa ń ṣe, ìjòyè aláìláàánú ni a ó rán sí i. Ó sàn kí ènìyàn pàdé beari tí a ti kó lọ́mọ jù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀. Bí ènìyàn kan bá fi ibi san ìre, ibi kì yóò kúrò nílé rẹ̀ láéláé. Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún omi nítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà.