Owe 16:17-33

Owe 16:17-33 YBCV

Òpopo-ọ̀na awọn aduro-ṣinṣin ni ati kuro ninu ibi: ẹniti o pa ọ̀na rẹ̀ mọ́, o pa ọkàn rẹ̀ mọ́. Igberaga ni iṣaju iparun, agidi ọkàn ni iṣaju iṣubu. O san lati ṣe onirẹlẹ ọkàn pẹlu awọn talaka, jù ati ba awọn agberaga pin ikógun. Ẹniti o fi oye ṣe ọ̀ran yio ri ire; ẹniti o si gbẹkẹ le Oluwa, ibukún ni fun u. Ọlọgbọ́n aiya li a o pè li amoye: didùn-ète a si ma mu ẹkọ́ pọ̀. Oye li orisun ìye fun ẹniti o ni i: ṣugbọn ẹkọ́ aṣiwère ni iwère. Aiya ọlọgbọ́n mu ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ gbọ́n, o si mu ẹkọ́ pọ̀ li ète rẹ̀. Ọrọ didùn dabi afara oyin, o dùn mọ ọkàn, o si ṣe ilera fun egungun. Ọ̀na kan wà ti o dabi ẹnipe o dara fun enia, ṣugbọn opin rẹ̀ li ọ̀na ikú. Ọkàn ti o nṣiṣẹ, o nṣiṣẹ fun ara rẹ̀; nitoripe ẹnu ara rẹ̀ li o nsún u ṣe e. Enia-buburu hù ìwa-ibi jade, ati li ète rẹ̀ bi ẹnipe iná jijo li o wà nibẹ. Alayidayida enia dá ìja silẹ: asọ̀rọkẹlẹ yà awọn ọrẹ́ ni ipa. Ẹni ìwa-agbara tàn aladugbo rẹ̀, a si mu u lọ si ipa-ọ̀na ti kò dara. On a di oju rẹ̀ lati gbèro ohun ayidayida: o ká ète rẹ̀ sinu, o pari ohun buburu. Ade ogo li ori ewú, bi a ba ri i li ọ̀na ododo. Ẹniti o lọra ati binu, o san jù alagbara lọ; ẹniti o si ṣe akoso ẹmi rẹ̀, o jù ẹniti o ṣẹgun ilu lọ. A ṣẹ́ keke dà si iṣẹpo aṣọ; ṣugbọn gbogbo idajọ rẹ̀ lọwọ Oluwa ni.

Àwọn àwòrán ẹsẹ fún Owe 16:17-33

Owe 16:17-33 - Òpopo-ọ̀na awọn aduro-ṣinṣin ni ati kuro ninu ibi: ẹniti o pa ọ̀na rẹ̀ mọ́, o pa ọkàn rẹ̀ mọ́.
Igberaga ni iṣaju iparun, agidi ọkàn ni iṣaju iṣubu.
O san lati ṣe onirẹlẹ ọkàn pẹlu awọn talaka, jù ati ba awọn agberaga pin ikógun.
Ẹniti o fi oye ṣe ọ̀ran yio ri ire; ẹniti o si gbẹkẹ le Oluwa, ibukún ni fun u.
Ọlọgbọ́n aiya li a o pè li amoye: didùn-ète a si ma mu ẹkọ́ pọ̀.
Oye li orisun ìye fun ẹniti o ni i: ṣugbọn ẹkọ́ aṣiwère ni iwère.
Aiya ọlọgbọ́n mu ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ gbọ́n, o si mu ẹkọ́ pọ̀ li ète rẹ̀.
Ọrọ didùn dabi afara oyin, o dùn mọ ọkàn, o si ṣe ilera fun egungun.
Ọ̀na kan wà ti o dabi ẹnipe o dara fun enia, ṣugbọn opin rẹ̀ li ọ̀na ikú.
Ọkàn ti o nṣiṣẹ, o nṣiṣẹ fun ara rẹ̀; nitoripe ẹnu ara rẹ̀ li o nsún u ṣe e.
Enia-buburu hù ìwa-ibi jade, ati li ète rẹ̀ bi ẹnipe iná jijo li o wà nibẹ.
Alayidayida enia dá ìja silẹ: asọ̀rọkẹlẹ yà awọn ọrẹ́ ni ipa.
Ẹni ìwa-agbara tàn aladugbo rẹ̀, a si mu u lọ si ipa-ọ̀na ti kò dara.
On a di oju rẹ̀ lati gbèro ohun ayidayida: o ká ète rẹ̀ sinu, o pari ohun buburu.
Ade ogo li ori ewú, bi a ba ri i li ọ̀na ododo.
Ẹniti o lọra ati binu, o san jù alagbara lọ; ẹniti o si ṣe akoso ẹmi rẹ̀, o jù ẹniti o ṣẹgun ilu lọ.
A ṣẹ́ keke dà si iṣẹpo aṣọ; ṣugbọn gbogbo idajọ rẹ̀ lọwọ Oluwa ni.