Òpópó ọ̀nà àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yàgò fún ibi, ẹni tí ó ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀, ṣọ́ ẹnu ara rẹ̀. Ìgbéraga ní í ṣáájú ìparun, agídí ọkàn ní í ṣáájú ìṣubú. Ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn láàrín àwọn olùpọ́njú jù láti máa pín ìpín pẹ̀lú àwọn agbéraga. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ yóò rí ìre, ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLúWA. Àwọn tí ó gbọ́n nínú ọkàn là ń pè ní olóye ọ̀rọ̀ ìtura sì ń mú ẹ̀kọ́ gbèrú. Òye jẹ́ orísun ìyè fún àwọn tí ó ní i, ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ ń kó ìyà jẹ aláìgbọ́n. Ọkàn ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀ ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ dàgbà. Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyin ó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun. Ọ̀nà kan tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn a ṣokùnfà ikú. Ọkàn alágbàṣe ń ṣiṣẹ́ fún ara rẹ̀; nítorí ebi rẹ̀ mú kí ó máa ṣiṣẹ́ lọ. Ènìyàn búburú ń pète ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dàbí i iná tí ń jóni. Aláyídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀ olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ní yà. Oníjàgídíjàgan ènìyàn tan aládùúgbò rẹ̀ ó sì mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà tí kò dára. Ẹni tí ń ṣẹ́jú ń pètekéte; ẹni tí ó ṣu ẹnu jọ ń pète aburú. Adé ògo ni ewú orí jẹ́, ìgbé ayé òdodo ní í mú ni dé bẹ̀. Ó sàn láti jẹ́ onísùúrù ju ajagun ènìyàn lọ, ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun ṣẹ́gun ìlú lọ. A ṣẹ́ kèké si ìṣẹ́po aṣọ, ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ OLúWA.
Kà Òwe 16
Feti si Òwe 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Òwe 16:17-33
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò