IDAHÙN pẹlẹ yi ibinu pada; ṣugbọn ọ̀rọ lile ni irú ibinu soke. Ahọn ọlọgbọ́n nlò ìmọ rere: ṣugbọn ẹnu aṣiwère a ma gufẹ wère. Oju Oluwa mbẹ ni ibi gbogbo, o nwò awọn ẹni-buburu ati ẹni-rere. Ahọn imularada ni igi ìye: ṣugbọn ayidayida ninu rẹ̀ ni ibajẹ ọkàn. Aṣiwère gàn ẹkọ́ baba rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba feti si ibawi li o moye. Ni ile olododo li ọ̀pọlọpọ iṣura: ṣugbọn ninu òwò enia buburu ni iyọnu. Ete ọlọgbọ́n tan ìmọ kalẹ: ṣugbọn aiya aṣiwère kì iṣe bẹ̃. Ẹbọ awọn enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn adura awọn aduroṣinṣin ni didùn-inu rẹ̀. Ọ̀na enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn o fẹ ẹniti ntọ̀ ododo lẹhin. Ikilọ kikan wà fun ẹniti o kọ̀ ọ̀na silẹ; ẹniti o ba si korira ibawi yio kú. Ipo-okú ati iparun ṣi silẹ niwaju Oluwa; njẹ melomelo li aiya awọn ọmọ enia. Ẹlẹgàn kò fẹ ẹniti mba a wi; bẹ̃ni kì yio tọ̀ awọn ọlọgbọ́n lọ. Inu-didùn a mu oju daraya; ṣugbọn nipa ibinujẹ aiya, ọkàn a rẹ̀wẹsi. Aiya ẹniti oye ye nṣe afẹri ìmọ; ṣugbọn ẹnu aṣiwère nfi wère bọ́ ara rẹ̀. Gbogbo ọjọ olupọnju ni ibi; ṣugbọn oninu-didùn njẹ alafia nigbagbogbo. Diẹ pẹlu ibẹ̀ru Oluwa, o san jù iṣura pupọ ti on ti iyọnu ninu rẹ̀. Onjẹ ewebẹ̀ nibiti ifẹ wà, o san jù abọpa malu lọ ati irira pẹlu rẹ̀.
Kà Owe 15
Feti si Owe 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Owe 15:1-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò