Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè. Ahọ́n ọlọ́gbọ́n a máa gbé ìmọ̀ jáde ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń tú ọ̀rọ̀ ọ òmùgọ̀ jáde. Ojú OLúWA wà níbi gbogbo, Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere. Ahọ́n tí ń mú ìtura wá jẹ́ igi ìyè ṣùgbọ́n ahọ́n ẹ̀tàn ń pa ẹ̀mí run. Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra, ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn. Ètè olódodo ń tan ìmọ̀ kalẹ̀; ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún ọkàn aláìgbọ́n. OLúWA kórìíra ìrúbọ àwọn ènìyàn búburú ṣùgbọ́n àdúrà olódodo tẹ́ ẹ lọ́rùn. OLúWA kórìíra ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ó fẹ́ràn àwọn tí ń lépa òdodo. Ẹni tí ó kúrò lójú ọ̀nà yóò rí ìbáwí gan an, ẹni tí ó kórìíra ìbáwí yóò kú. Ikú àti ìparun ṣí sílẹ̀ níwájú OLúWA, mélòó mélòó ní nínú ọkàn àwọn ènìyàn. Ẹlẹ́gàn kò fẹ́ ẹni tí ń ba wí: kò ní gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ọlọ́gbọ́n. Inú dídùn máa ń mú kí ojú túká ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ọkàn máa ń pa ẹ̀mí run. Ọkàn olóye ń wá ìmọ̀ ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń fẹ́ ìwà òmùgọ̀ bí ẹní jẹun. Gbogbo ọjọ́ àwọn olùpọ́njú jẹ́ ibi, ṣùgbọ́n onínúdídùn ń jẹ àlàáfíà ní ìgbà gbogbo. Ó sàn kí ó má pọ̀, kí ìbẹ̀rù OLúWA sì wà ju ọrọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú ìyọnu. Oúnjẹ ewébẹ̀ níbi tí ìfẹ́ wà sàn ju àbọ́pa màlúù tòun ti ìríra.
Kà Òwe 15
Feti si Òwe 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Òwe 15:1-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò