ÌWÉ ÒWE 15:1-17

ÌWÉ ÒWE 15:1-17 YCE

Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ a máa mú kí ibinu rọlẹ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ líle níí ru ibinu sókè. Lẹ́nu ọlọ́gbọ́n ni ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ti ń jáde, ṣugbọn òmùgọ̀ a máa sọ̀rọ̀ agọ̀. Ojú OLUWA wà níbi gbogbo, ó ń ṣọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere. Ọ̀rọ̀ tí a fi pẹ̀lẹ́ sọ dàbí igi ìyè, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn a máa bani lọ́kàn jẹ́. Òmùgọ̀ ọmọ á kẹ́gàn ìtọ́sọ́nà baba rẹ̀, ṣugbọn ọmọ tí ó gbọ́ ìkìlọ̀, ọlọ́gbọ́n ni. Ilé olódodo kún fún ọpọlọpọ ìṣúra, ṣugbọn kìkì ìdààmú ni àkójọ èrè eniyan burúkú. Ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa tan ìmọ̀ kálẹ̀, ṣugbọn ti òmùgọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Ohun ìríra ni ẹbọ eniyan burúkú lójú OLUWA, ṣugbọn adura olódodo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀. OLUWA kórìíra ìwà àwọn eniyan burúkú, ṣugbọn ó fẹ́ràn àwọn tí ń hùwà òdodo. Ìbáwí pupọ ń bẹ fún ẹni tí ó yapa kúrò ní ọ̀nà rere, ẹni tí ó bá kórìíra ìbáwí yóo kú. Isà òkú ati ìparun kò pamọ́ lójú OLUWA, mélòó-mélòó ni ọkàn eniyan. Inú pẹ̀gànpẹ̀gàn kì í dùn sí ìbáwí, kì í bèèrè ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ọlọ́gbọ́n. Inú dídùn a máa múni dárayá, ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí ojú eniyan rẹ̀wẹ̀sì. Ẹni tí ó ní òye a máa wá ìmọ̀, ṣugbọn agọ̀ ni oúnjẹ òmùgọ̀. Gbogbo ọjọ́ ayé ẹni tí a ni lára kún fún ìpọ́njú, ṣugbọn ojoojumọ ni ọdún fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn. Ó sàn kí á jẹ́ talaka, kí á sì ní ìbẹ̀rù OLUWA, ju kí á jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí á sì kún fún ìyọnu lọ. Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ pẹlu ìfẹ́, sàn ju ẹran mààlúù tòun ti ìkórìíra lọ.