Num 14:6-8

Num 14:6-8 YBCV

Ati Joṣua ọmọ Nuni ati Kalebu ọmọ Jefunne, ti o wà ninu awọn ti o ṣe amí ilẹ na, fà aṣọ wọn ya: Nwọn si sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, wipe, Ilẹ na ti awa là já lati ṣe amí rẹ̀, ilẹ na dara gidigidi. Bi OLUWA ba fẹ́ wa, njẹ yio mú wa wọ̀ inu ilẹ na yi, yio si fi i fun wa; ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.