Num 14:6-8
Num 14:6-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati Joṣua ọmọ Nuni ati Kalebu ọmọ Jefunne, ti o wà ninu awọn ti o ṣe amí ilẹ na, fà aṣọ wọn ya: Nwọn si sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, wipe, Ilẹ na ti awa là já lati ṣe amí rẹ̀, ilẹ na dara gidigidi. Bi OLUWA ba fẹ́ wa, njẹ yio mú wa wọ̀ inu ilẹ na yi, yio si fi i fun wa; ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.

Num 14:6-8 Yoruba Bible (YCE)
Joṣua ọmọ Nuni ati Kalebu ọmọ Jefune tí wọ́n wà lára àwọn amí fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn. Wọ́n sọ fún ìjọ eniyan Israẹli pé, “Ilẹ̀ tí a lọ wò náà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára lọpọlọpọ. Bí inú OLUWA bá dùn sí wa, yóo mú wa dé ilẹ̀ náà, yóo sì fún wa; àní ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati fún oyin, ilẹ̀ ọlọ́ràá tí ó lẹ́tù lójú.
Num 14:6-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Joṣua ọmọ Nuni àti Kalebu ọmọ Jefunne, tí wọ́n wà lára àwọn to lọ yẹ ilẹ̀ wò sì fa aṣọ wọn ya. Wọ́n sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli pé, “Ilẹ̀ tí a là kọjá láti yẹ̀ wò náà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀. Bí inú OLúWA bá dùn sí wa, yóò mú wa dé ilẹ̀ náà, ilẹ̀ tó ń sàn fún wàrà àti fún oyin, yóò fún wa ní ilẹ̀ náà.