Num 14

14
Àwọn Eniyan náà Kùn
1GBOGBO ijọ si gbé ohùn wọn soke, nwọn si ke: awọn enia na si sọkun li oru na.
2Gbogbo awọn ọmọ Israeli si nkùn si Mose ati si Aaroni: gbogbo ijọ si wi fun wọn pe, Awa iba kuku ti kú ni ilẹ Egipti! tabi awa iba kú li aginjù yi!
3Nitori kini OLUWA ṣe mú wa wá si ilẹ yi, lati ti ipa idà ṣubu? Awọn aya wa, ati awọn ọmọ wa yio di ijẹ: kò ha san fun wa ki a pada lọ si Egipti?
4Nwọn si wi fun ara wọn pe, Ẹ jẹ ki a yàn olori, ki a si pada lọ si Egipti.
5Nigbana ni Mose ati Aaroni doju wọn bolẹ niwaju gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli.
6Ati Joṣua ọmọ Nuni ati Kalebu ọmọ Jefunne, ti o wà ninu awọn ti o ṣe amí ilẹ na, fà aṣọ wọn ya:
7Nwọn si sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, wipe, Ilẹ na ti awa là já lati ṣe amí rẹ̀, ilẹ na dara gidigidi.
8Bi OLUWA ba fẹ́ wa, njẹ yio mú wa wọ̀ inu ilẹ na yi, yio si fi i fun wa; ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.
9Ṣugbọn ẹ máṣe ṣọ̀tẹ si OLUWA, bẹ̃ni ki ẹ máṣe bẹ̀ru awọn enia ilẹ na; nitoripe onjẹ wa ni nwọn; àbo wọn ti fi wọn silẹ, OLUWA si wà pẹlu wa: ẹ máṣe bẹ̀ru wọn.
10Gbogbo ijọ si wipe ki a sọ wọn li okuta. Ṣugbọn ogo OLUWA hàn ninu agọ́ ajọ niwaju gbogbo awọn ọmọ Israeli.
Mose Gbadura fún Àwọn Eniyan náà
11OLUWA si wi fun Mose pe, Awọn enia yi yio ti kẹgàn mi pẹ tó? yio si ti pẹ tó ti nwọn o ṣe alaigbà mi gbọ́, ni gbogbo iṣẹ-àmi ti mo ṣe lãrin wọn?
12Emi o fi ajakalẹ-àrun kọlù wọn, emi o si gbà ogún wọn lọwọ wọn, emi o si sọ iwọ di orilẹ-ède nla, ati alagbara jù wọn lọ.
13Mose si wi fun OLUWA pe, Ṣugbọn awọn ara Egipti yio gbọ́; nitoripe nipa agbara rẹ ni iwọ fi mú awọn enia yi jade lati inu wọn wá;
14Nwọn o si wi fun awọn ara ilẹ yi: nwọn sá ti gbọ́ pe iwọ OLUWA mbẹ lãrin awọn enia yi, nitoripe a ri iwọ OLUWA li ojukoju, ati pe awọsanma rẹ duro lori wọn, ati pe iwọ li o ṣaju wọn, ninu ọwọ̀n awọsanma nigba ọsán, ati ninu ọwọ̀n iná li oru.
15Njẹ bi iwọ ba pa gbogbo awọn enia yi bi ẹnikan, nigbana li awọn orilẹ-ède ti o ti gbọ́ okikí rẹ yio wipe,
16Nitoriti OLUWA kò le mú awọn enia yi dé ilẹ ti o ti fi bura fun wọn, nitorina li o ṣe pa wọn li aginjù.
17Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki agbara OLUWA ki o tobi, gẹgẹ bi iwọ ti sọ rí pe,
18Olupamọra ati ẹniti o pọ̀ li ãnu li OLUWA, ti ndari ẹ̀ṣẹ ati irekọja jì, ati bi o ti wù ki o ri, ti ki ijẹ ki ẹlẹbi lọ laijìya; a ma bẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, titi dé iran kẹta ati ẹkẹrin.
19Emi bẹ̀ ọ, dari ẹ̀ṣẹ awọn enia yi jì, gẹgẹ bi titobi ãnu rẹ, ati bi iwọ ti darijì awọn enia yi, lati Egipti titi di isisiyi.
20OLUWA si wipe, Emi ti darijì gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ:
21Ṣugbọn nitõtọ, bi mo ti wà, gbogbo aiye yio si kún fun ogo OLUWA;
22Nitori gbogbo awọn enia wọnyi ti o ti ri ogo mi, ati iṣẹ-àmi mi, ti mo ti ṣe ni Egipti ati li aginjù, ti nwọn si dan mi wò nigba mẹwa yi, ti nwọn kò si fetisi ohùn mi;
23Nitõtọ nwọn ki yio ri ilẹ na ti mo ti fi bura fun awọn baba wọn, bẹ̃ni ọkan ninu awọn ti o gàn mi ki yio ri i:
24Ṣugbọn Kalebu iranṣẹ mi, nitoriti o ní ọkàn miran ninu rẹ̀, ti o si tẹle mi mọtimọti, on li emi o múlọ sinu ilẹ na nibiti o ti rè; irú-ọmọ rẹ̀ ni yio si ní i.
25Njẹ awọn ara Amaleki ati awọn ara Kenaani ngbé afonifoji: li ọla ẹ pada, ki ẹ si ṣi lọ si aginjù nipa ọ̀na Okun Pupa.
OLUWA Jẹ Àwọn Eniyan náà Níyà Nítorí pé wọ́n Kùn
26OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,
27Emi o ti mu sũru pẹ to fun ijọ enia buburu yi ti nkùn si mi? Emi ti gbọ́ kikùn awọn ọmọ Israeli, ti nwọn kùn si mi.
28Wi fun wọn pe, OLUWA wipe, Bi mo ti wà nitõtọ, bi ẹnyin ti sọ li etí mi, bẹ̃li emi o ṣe si nyin:
29Okú nyin yio ṣubu li aginjù yi; ati gbogbo awọn ti a kà ninu nyin, gẹgẹ bi iye gbogbo nyin, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jú bẹ̃ lọ, ti ẹ kùn si mi,
30Ẹnyin ki yio dé inu ilẹ na, ti mo ti bura lati mu nyin gbé inu rẹ̀, bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne, ati Joṣua ọmọ Nuni.
31Ṣugbọn awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ti ẹnyin wipe yio di ijẹ, awọn li emi o muwọ̀ ọ, awọn ni yio si mọ̀ ilẹ na ti ẹnyin gàn.
32Ṣugbọn ẹnyin, okú nyin yio ṣubu li aginjú yi.
33Awọn ọmọ nyin yio si ma rìn kiri li aginjù li ogoji ọdún, nwọn o si ma rù ìwa-àgbere nyin, titi okú nyin yio fi ṣòfo tán li aginjù.
34Gẹgẹ bi iye ọjọ́ ti ẹnyin fi rìn ilẹ na wò, ani ogoji ọjọ́, ọjọ́ kan fun ọdún kan, li ẹnyin o rù ẹ̀ṣẹ nyin, ani ogoji ọdún, ẹnyin o si mọ̀ ibà ileri mi jẹ́.
35Emi OLUWA ti sọ, Emi o ṣe e nitõtọ si gbogbo ijọ buburu yi, ti nwọn kójọ pọ̀ si mi: li aginjù yi ni nwọn o run, nibẹ̀ ni nwọn o si kú si.
36Ati awọn ọkunrin na ti Mose rán lọ lati rìn ilẹ na wò, ti nwọn pada, ti nwọn si mu gbogbo ijọ kùn si i, ni mimú ìhin buburu ilẹ na wá,
37Ani awọn ọkunrin na ti o mú ìhin buburu ilẹ na wá, nwọn ti ipa àrun kú niwaju OLUWA.
38Ṣugbọn Joṣua ọmọ Nuni, ati Kalebu ọmọ Jefunne, ninu awọn ọkunrin na ti o rìn ilẹ na lọ, wà lãye.
Ìgbà Kinni Tí Wọ́n Gbìyànjú àtigba Ilẹ̀ náà
(Deu 1:41-46)
39Mose si sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli: awọn enia na si kãnu gidigidi.
40Nwọn si dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si gùn ori òke nì lọ, wipe, Kiyesi i, awa niyi, awa o si gòke lọ si ibiti OLUWA ti ṣe ileri: nitoripe awa ti ṣẹ̀.
41Mose si wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nre aṣẹ OLUWA kọja? kì yio sa gbè nyin.
42Ẹ máṣe gòke lọ, nitoriti OLUWA kò sí lãrin nyin, ki a má ba lù nyin bolẹ niwaju awọn ọtá nyin.
43Nitoriti awọn ara Amaleki ati awọn ara Kenaani mbẹ niwaju nyin, ẹnyin o si ti ipa idà ṣubu: nitoriti ẹnyin ti yipada kuro lẹhin OLUWA, nitorina OLUWA ki yio si pẹlu nyin.
44Ṣugbọn nwọn fi igberaga gòke lọ sori òke na: ṣugbọn apoti ẹrí OLUWA, ati Mose, kò jade kuro ni ibudò.
45Nigbana li awọn ara Amaleki sọkalẹ wá, ati awọn ara Kenaani ti ngbé ori-òke na, nwọn si kọlù wọn nwọn si ṣẹ́ wọn titi dé Horma.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Num 14: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀