Num 13

13
Mose Rán Amí lọ sí Ilẹ̀ Kenaani
(Deu 1:19-33)
1OLUWA si sọ fun Mose pe,
2Rán enia, ki nwọn ki o si ṣe amí ilẹ Kenaani, ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli: ọkunrin kan ni ki ẹnyin ki o rán ninu ẹ̀ya awọn baba wọn, ki olukuluku ki o jẹ́ ijoye ninu wọn.
3Mose si rán wọn lati ijù Parani lọ, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA: gbogbo awọn ọkunrin na jẹ́ olori awọn ọmọ Israeli.
4Orukọ wọn si ni wọnyi: ninu ẹ̀ya Reubeni, Ṣammua ọmọ Sakuru.
5Ninu ẹ̀ya Simeoni, Ṣafati ọmọ Hori.
6Ninu ẹ̀ya Juda, Kalebu ọmọ Jefunne.
7Ninu ẹ̀ya Issakari, Igali ọmọ Josefu.
8Ninu ẹ̀ya Efraimu, Oṣea ọmọ Nuni.
9Ninu ẹ̀ya Benjamini, Palti ọmọ Rafu.
10Ninu ẹ̀ya Sebuluni, Gaddieli ọmọ Sodi.
11Ninu ẹ̀ya Josefu, eyinì ni, ninu ẹ̀ya Manasse, Gadi ọmọ Susi.
12Ninu ẹ̀ya Dani, Ammieli ọmọ Gemalli.
13Ninu ẹ̀ya Aṣeri, Seturu ọmọ Mikaeli.
14Ninu ẹ̀ya Naftali, Nabi ọmọ Fofsi.
15Ninu ẹ̀ya Gaddi, Geueli ọmọ Maki.
16Wọnyi li orukọ awọn ọkunrin na, ti Mose rán lati lọ ṣe amí ilẹ na. Mose si sọ Oṣea ọmọ Nuni ni Joṣua.
17Mose si rán wọn lọ ṣe amí ilẹ Kenaani, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbà ọ̀na ìha gusù yi, ki ẹ sì lọ sori òke nì.
18Ki ẹnyin si wò ilẹ na, bi o ti ri; ati awọn enia ti ngbé inu rẹ̀, bi nwọn ṣe alagbara tabi alailagbara, bi diẹ ni nwọn, tabi pupọ̀;
19Ati bi ilẹ na ti nwọn ngbé ti ri, bi didara ni bi buburu ni; ati bi ilu ti nwọn ngbé ti ri, bi ninu agọ́ ni, tabi ninu ilu odi;
20Ati bi ilẹ na ti ri, bi ẹlẹtu ni tabi bi aṣalẹ̀, bi igi ba mbẹ ninu rẹ̀, tabi kò sí. Ki ẹnyin ki o si mu ọkàn le, ki ẹnyin si mú ninu eso ilẹ na wá. Njẹ ìgba na jẹ́ akokò pipọn akọ́so àjara.
21Bẹ̃ni nwọn gòke lọ, nwọn si ṣe amí ilẹ na lati ijù Sini lọ dé Rehobu, ati lọ si Hamati.
22Nwọn si ti ìha gusù gòke lọ, nwọn si dé Hebroni; nibiti Ahimani, Ṣeṣai, ati Talmai, awọn ọmọ Anaki gbé wà. (A ti tẹ̀ Hebroni dò li ọdún meje ṣaju Soani ni Egipti.)
23Nwọn si dé odò Eṣkolu, nwọn si rẹ́ ọwọ́ àjara kan, ti on ti ìdi eso-àjara kan lati ibẹ̀ wá, awọn enia meji si fi ọpá rù u; nwọn si mú ninu eso-pomegranate, ati ti ọpọtọ́ wá.
24Nwọn si sọ ibẹ̀ na ni odò Eṣkolu, nitori ìdi-eso ti awọn ọmọ Israeli rẹ́ lati ibẹ̀ wá.
25Nwọn si pada ni rirìn ilẹ na wò lẹhin ogoji ọjọ́.
26Nwọn si lọ nwọn tọ̀ Mose wá, ati Aaroni, ati gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ni ijù Parani, ni Kadeṣi; nwọn si mú ọ̀rọ pada tọ̀ wọn wá, ati gbogbo ijọ, nwọn si fi eso ilẹ na hàn wọn.
27Nwọn si rò fun u, nwọn si wipe, Awa dé ilẹ na nibiti iwọ gbé rán wa lọ, nitõtọ li o nṣàn fun warà ati fun oyin; eyi si li eso rẹ̀.
28Ṣugbọn alagbara ni awọn enia ti ngbé inu ilẹ na, ilu olodi si ni ilu wọn, nwọn tobi gidigidi: ati pẹlupẹlu awa ri awọn ọmọ Anaki nibẹ̀.
29Awọn ara Amaleki si ngbé ilẹ ìha gusù: ati awọn Hitti, ati awọn Jebusi, ati awọn Amori, ngbé ori-òke: awọn ara Kenaani si ngbé ẹba okun, ati ni àgbegbe Jordani.
30Kalebu si pa awọn enia lẹnu mọ́ niwaju Mose, o si wipe, Ẹ jẹ ki a gòke lọ lẹ̃kan, ki a si gbà a; nitoripe awa le ṣẹ́ ẹ.
31Ṣugbọn awọn ọkunrin ti o bá a gòke lọ wipe, Awa kò le gòke tọ̀ awọn enia na lọ; nitoriti nwọn lagbara jù wa lọ.
32Nwọn si mú ìhin buburu ti ilẹ na, ti nwọn ti ṣe amí wá fun awọn ọmọ Israeli, wipe, Ilẹ na ti awa là já lati ṣe amí rẹ̀, ilẹ ti imu awọn enia rẹ̀ jẹ ni; ati gbogbo enia ti awa ri ninu rẹ̀ jẹ́ enia ti o ṣigbọnlẹ.
33Ati nibẹ̀ li awa gbé ri awọn omirán, awọn ọmọ Anaki ti o ti inu awọn omirán wá: awa si dabi ẹlẹnga li oju ara wa, bẹ̃li awa si ri li oju wọn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Num 13: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa