Nigbati o si ti inu ọkọ̀ jade, lojukanna ọkunrin kan ti o li ẹmi aimọ pade rẹ̀, o nti ibi ibojì jade wá,
Ẹniti o ni ibugbe rẹ̀ ninu ibojì; kò si si ẹniti o le dè e, kò si, kì iṣe ẹ̀wọn:
Nitoripe nigbapupọ li a ti nfi ṣẹkẹṣẹkẹ ati ẹ̀wọn de e, on a si dá ẹ̀wọn na meji, a si dá ṣẹkẹṣẹkẹ wẹ́wẹ: bẹ̃ni kò si ẹnikan ti o li agbara lati se e rọ̀.
Ati nigbagbogbo, li ọsán ati li oru, o wà lori òke, ati ninu ibojì, a ma kigbe, a si ma fi okuta pa ara rẹ̀ lara.
Ṣugbọn nigbati o ri Jesu li òkere, o sare wá, o si foribalẹ fun u,
O si nkigbe li ohùn rara, wipe, Kini ṣe temi tirẹ, Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun Ọgá-ogo? mo fi Ọlọrun bẹ̀ ọ, ki iwọ ki o máṣe da mi loró.
Nitoriti o wi fun u pe, Jade kuro lara ọkunrin na, iwọ ẹmi aimọ́.
O si bi i lẽre pe, Orukọ rẹ? O si dahùn, wipe, Legioni li orukọ mi: nitori awa pọ̀.
O si bẹ̀ ẹ gidigidi pe, ki o máṣe rán wọn jade kuro ni ilẹ na.