MAKU 5:2-10

MAKU 5:2-10 YCE

Bí ó ti jáde kúrò ninu ọkọ̀, ọkunrin wèrè kan wá pàdé rẹ̀ láti inú ibojì pàlàpálá àpáta. Ibojì náà ni ò fi ṣe ilé. Kò sí ẹni tí ó lè de wèrè náà mọ́lẹ̀; ẹ̀wọ̀n kò tilẹ̀ ṣe é fi dè é. Nítorí ní ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n kó ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lẹ́sẹ̀, tí wọ́n tún fi ẹ̀wọ̀n dè é lọ́wọ́. Ṣugbọn jíjá ni ó máa ń já ẹ̀wọ̀n, tí ó sì máa ń rún ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n fi dè é. Kò sí ẹni tí ó lè fi agbára mú un kí ó fi ara balẹ̀. Tọ̀sán-tòru níí máa kígbe láàrin àwọn ibojì ati lórí òkè, a sì máa fi òkúta ya ara rẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí ó rí Jesu lókèèrè, ó sáré, ó dọ̀bálẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó ké rara pé, “Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ọmọ Ọlọrun tí ó lógo jùlọ? Mo fi Ọlọrun bẹ̀ ọ́, má ṣe dá mi lóró.” (Nítorí Jesu tí ń sọ pé kí ẹ̀mí èṣù náà jáde kúrò ninu ọkunrin náà.) Jesu wá bi í pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó ní, “Ẹgbaagbeje ni mò ń jẹ́, nítorí a kò níye.” Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ Jesu títí pé kí ó má ṣe lé wọn jáde kúrò ní agbègbè ibẹ̀.

Àwọn fídíò fún MAKU 5:2-10