Mak 5:2-10
Mak 5:2-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o si ti inu ọkọ̀ jade, lojukanna ọkunrin kan ti o li ẹmi aimọ pade rẹ̀, o nti ibi ibojì jade wá, Ẹniti o ni ibugbe rẹ̀ ninu ibojì; kò si si ẹniti o le dè e, kò si, kì iṣe ẹ̀wọn: Nitoripe nigbapupọ li a ti nfi ṣẹkẹṣẹkẹ ati ẹ̀wọn de e, on a si dá ẹ̀wọn na meji, a si dá ṣẹkẹṣẹkẹ wẹ́wẹ: bẹ̃ni kò si ẹnikan ti o li agbara lati se e rọ̀. Ati nigbagbogbo, li ọsán ati li oru, o wà lori òke, ati ninu ibojì, a ma kigbe, a si ma fi okuta pa ara rẹ̀ lara. Ṣugbọn nigbati o ri Jesu li òkere, o sare wá, o si foribalẹ fun u, O si nkigbe li ohùn rara, wipe, Kini ṣe temi tirẹ, Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun Ọgá-ogo? mo fi Ọlọrun bẹ̀ ọ, ki iwọ ki o máṣe da mi loró. Nitoriti o wi fun u pe, Jade kuro lara ọkunrin na, iwọ ẹmi aimọ́. O si bi i lẽre pe, Orukọ rẹ? O si dahùn, wipe, Legioni li orukọ mi: nitori awa pọ̀. O si bẹ̀ ẹ gidigidi pe, ki o máṣe rán wọn jade kuro ni ilẹ na.
Mak 5:2-10 Yoruba Bible (YCE)
Bí ó ti jáde kúrò ninu ọkọ̀, ọkunrin wèrè kan wá pàdé rẹ̀ láti inú ibojì pàlàpálá àpáta. Ibojì náà ni ò fi ṣe ilé. Kò sí ẹni tí ó lè de wèrè náà mọ́lẹ̀; ẹ̀wọ̀n kò tilẹ̀ ṣe é fi dè é. Nítorí ní ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n kó ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lẹ́sẹ̀, tí wọ́n tún fi ẹ̀wọ̀n dè é lọ́wọ́. Ṣugbọn jíjá ni ó máa ń já ẹ̀wọ̀n, tí ó sì máa ń rún ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n fi dè é. Kò sí ẹni tí ó lè fi agbára mú un kí ó fi ara balẹ̀. Tọ̀sán-tòru níí máa kígbe láàrin àwọn ibojì ati lórí òkè, a sì máa fi òkúta ya ara rẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí ó rí Jesu lókèèrè, ó sáré, ó dọ̀bálẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó ké rara pé, “Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ọmọ Ọlọrun tí ó lógo jùlọ? Mo fi Ọlọrun bẹ̀ ọ́, má ṣe dá mi lóró.” (Nítorí Jesu tí ń sọ pé kí ẹ̀mí èṣù náà jáde kúrò ninu ọkunrin náà.) Jesu wá bi í pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó ní, “Ẹgbaagbeje ni mò ń jẹ́, nítorí a kò níye.” Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ Jesu títí pé kí ó má ṣe lé wọn jáde kúrò ní agbègbè ibẹ̀.
Mak 5:2-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí Jesu sì ti ń ti inú ọkọ̀ ojú omi jáde. Ọkùnrin kan tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́ jáde ti ibojì wá pàdé rẹ̀. Ọkùnrin yìí ń gbé nínú ibojì, kò sí ẹni tí ó lè dè é mọ́, kódà ẹ̀wọ̀n kò le dè é. Nítorí pé nígbà púpọ̀ ni wọ́n ti ń fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀, tí ó sì ń já a dànù kúrò ni ẹsẹ̀ rẹ̀. Kò sí ẹnìkan tí ó ní agbára láti káwọ́ rẹ̀. Tọ̀sán tòru láàrín àwọn ibojì àti ní àwọn òkè ni ó máa ń kígbe rara tí ó sì ń fi òkúta ya ara rẹ̀. Nígbà tí ó sì rí Jesu látòkèrè, ó sì sáré lọ láti pàdé rẹ̀. Ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tèmi tìrẹ, Jesu Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo? Mo fi Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.” Nítorí tí Ó wí fún un pé, “Jáde kúrò lára ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́!” Jesu sì bi í léèrè pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì dáhùn wí pé, “Ligioni, nítorí àwa pọ̀.” Nígbà náà ni ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jesu gidigidi, kí ó má ṣe rán àwọn jáde kúrò ní agbègbè náà.