Nigbati iwọ ba ngbadura, máṣe dabi awọn agabagebe; nitori nwọn fẹ ati mã duro gbadura ni sinagogu ati ni igun ọ̀na ita, ki enia ki o ba le ri wọn. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na. Ṣugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbadura, wọ̀ iyẹwu rẹ lọ, nigbati iwọ ba si sé ilẹkùn rẹ tan, gbadura si Baba rẹ ti mbẹ ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ yio san a fun ọ ni gbangba. Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba ngbadura, ẹ máṣe atunwi asan bi awọn keferi; nwọn ṣebi a o ti itori ọ̀rọ pipọ gbọ́ ti wọn. Nitorina ki ẹnyin máṣe dabi wọn: Baba nyin sá mọ̀ ohun ti ẹnyin ṣe alaini, ki ẹ to bère lọwọ rẹ̀. Nitorina bayi ni ki ẹnyin mã gbadura: Baba wa ti mbẹ li ọrun; Ki a bọ̀wọ fun orukọ rẹ.
Kà Mat 6
Feti si Mat 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mat 6:5-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò