“Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ má ṣe bí àwọn aláṣehàn. Nítorí wọ́n fẹ́ràn kí wọ́n máa dúró gbadura ninu ilé ìpàdé ati ní ẹ̀bá títì, kí àwọn eniyan lè rí wọn. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ṣugbọn nígbà tí ìwọ bá ń gbadura, wọ inú yàrá rẹ lọ, ti ìlẹ̀kùn rẹ, kí o gbadura sí Baba rẹ tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, yóo san ẹ̀san rẹ fún ọ. “Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ má máa wí nǹkankan náà títí, bí àwọn abọ̀rìṣà ti ń ṣe. Nítorí wọ́n rò pé nípa ọ̀rọ̀ pupọ ni adura wọn yóo ṣe gbà. Ẹ má ṣe fara wé wọn, nítorí Baba yín ti mọ ohun tí ẹ nílò kí ẹ tó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ̀yin máa gbadura: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run: Kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ mímọ́ rẹ
Kà MATIU 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MATIU 6:5-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò