Ẹk. Jer 2:6-10

Ẹk. Jer 2:6-10 YBCV

O si ti wó ọgba rẹ̀ lulẹ, gẹgẹ bi àgbala: o ti pa ibi apejọ rẹ̀ run: Oluwa ti mu ki a gbagbe ajọ-mimọ́ ati ọjọ isimi ni Sioni, o ti fi ẹ̀gan kọ̀ ọba ati alufa silẹ ninu ikannu ibinu rẹ̀. Oluwa ti ṣá pẹpẹ rẹ̀ tì, o ti korira ibi-mimọ́ rẹ̀, o ti fi ogiri ãfin rẹ̀ le ọwọ ọta; nwọn ti pa ariwo ninu ile Oluwa, gẹgẹ bi li ọjọ ajọ-mimọ́. Oluwa ti rò lati pa odi ọmọbinrin Sioni run: o ti nà okùn ìwọn jade, on kò ti ifa ọwọ rẹ̀ sẹhin kuro ninu ipanirun: bẹ̃ni o ṣe ki ile-iṣọ rẹ̀ ati odi rẹ̀ ki o ṣọ̀fọ; nwọn jumọ rẹ̀ silẹ. Ẹnu-bode rẹ̀ wọnni rì si ilẹ; o ti parun o si ṣẹ́ ọpá idabu rẹ̀; ọba rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀ wà lãrin awọn orilẹ-ède: ofin kò si mọ; awọn woli rẹ̀ pẹlu kò ri iran lati ọdọ Oluwa. Awọn àgbagba ọmọbinrin Sioni joko ni ilẹ, nwọn dakẹ: nwọn ti ku ekuru sori wọn; nwọn ti fi aṣọ-ọ̀fọ di ara wọn: awọn wundia Jerusalemu sọ ori wọn kọ́ si ilẹ.