Ẹk. Jer 2:6-10
Ẹk. Jer 2:6-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ti wó ọgba rẹ̀ lulẹ, gẹgẹ bi àgbala: o ti pa ibi apejọ rẹ̀ run: Oluwa ti mu ki a gbagbe ajọ-mimọ́ ati ọjọ isimi ni Sioni, o ti fi ẹ̀gan kọ̀ ọba ati alufa silẹ ninu ikannu ibinu rẹ̀. Oluwa ti ṣá pẹpẹ rẹ̀ tì, o ti korira ibi-mimọ́ rẹ̀, o ti fi ogiri ãfin rẹ̀ le ọwọ ọta; nwọn ti pa ariwo ninu ile Oluwa, gẹgẹ bi li ọjọ ajọ-mimọ́. Oluwa ti rò lati pa odi ọmọbinrin Sioni run: o ti nà okùn ìwọn jade, on kò ti ifa ọwọ rẹ̀ sẹhin kuro ninu ipanirun: bẹ̃ni o ṣe ki ile-iṣọ rẹ̀ ati odi rẹ̀ ki o ṣọ̀fọ; nwọn jumọ rẹ̀ silẹ. Ẹnu-bode rẹ̀ wọnni rì si ilẹ; o ti parun o si ṣẹ́ ọpá idabu rẹ̀; ọba rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀ wà lãrin awọn orilẹ-ède: ofin kò si mọ; awọn woli rẹ̀ pẹlu kò ri iran lati ọdọ Oluwa. Awọn àgbagba ọmọbinrin Sioni joko ni ilẹ, nwọn dakẹ: nwọn ti ku ekuru sori wọn; nwọn ti fi aṣọ-ọ̀fọ di ara wọn: awọn wundia Jerusalemu sọ ori wọn kọ́ si ilẹ.
Ẹk. Jer 2:6-10 Yoruba Bible (YCE)
Ó wó àgọ́ rẹ̀ lulẹ̀, bí ìgbà tí eniyan wó ahéré oko. Ó pa gbogbo ibi tí wọ́n ti ń ṣe àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ run. OLUWA ti fi òpin sí àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀, ati ọjọ́ ìsinmi ní Sioni. Ó sì ti fi ibinu gbígbóná rẹ̀, kọ ọba ati alufaa sílẹ̀. OLUWA kò bìkítà fún pẹpẹ rẹ̀ mọ́, ó sì ti kọ ibi mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Ó ti fi odi ààfin rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́; wọ́n pariwo ńlá ninu ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bíi ti ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀. OLUWA ti pinnu láti wó odi Sioni lulẹ̀. Ó fi okùn ìwọ̀n wọ̀n ọ́n, kò sì rowọ́ láti parun. Ó jẹ́ kí ilé ìṣọ́ ati odi ìlú wó lulẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́, wọ́n sì di àlàpà papọ̀. Àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti rì, wọ́n ti wọlẹ̀; ó ti ṣẹ́ àwọn ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè; ọba rẹ̀ ati àwọn olórí rẹ̀ wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn; òfin kò sí mọ́, àwọn wolii rẹ̀ kò sì ríran láti ọ̀dọ̀ OLUWA mọ́. Àwọn àgbààgbà Sioni jókòó lórí ilẹ̀, wọ́n dákẹ́ rọ́rọ́, wọ́n ku eruku sórí, wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀. Àwọn ọmọbinrin Jerusalẹmu doríkodò.
Ẹk. Jer 2:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó mú ìparun bá ibi mímọ́, ó pa ibi ìpàdé rẹ̀ run. OLúWA ti mú Sioni gbàgbé àjọ̀dún tí a yàn àti ọ̀sẹ̀ tí ó yàn; nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó run ọba àti olórí àlùfáà. Olúwa ti kọ̀ pẹpẹ rẹ̀ sílẹ̀ ó sì ti kọ̀ ibi mímọ́ rẹ̀. Ó sì fi lé ọ̀tá lọ́wọ́ àwọn odi ààfin rẹ̀; wọ́n sì kígbe ní ilé OLúWA gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àpèjẹ tí a yàn. OLúWA pinnu láti fa ògiri tí ó yí ọmọbìnrin Sioni ya. Ó gbé wọn sórí òṣùwọ̀n, kò sì fa ọwọ́ rẹ̀ padà kúrò nínú ìparun wọn. Ó mú kí ilé ìṣọ́ àti odi rẹ̀ ṣọ̀fọ̀ wọ́n ṣòfò papọ̀. Ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ti wọ inú ilẹ̀; òpó rẹ̀ ni ó wó tí ó sì ti bàjẹ́. Ọba àti ọmọ ọbakùnrin rẹ̀ wà ní ìgbèkùn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, kò sí òfin mọ́, àwọn wòlíì rẹ̀ kò rí ìran láti ọ̀dọ̀ OLúWA mọ́. Àwọn àgbàgbà ọmọbìnrin Sioni jókòó sílẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́; wọ́n da eruku sí orí wọn wọ́n sì wọ aṣọ àkísà. Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Jerusalẹmu ti tẹrí wọn ba sí ilẹ̀.