Jon 1:7-10

Jon 1:7-10 YBCV

Olukuluku wọn si wi fun ẹgbẹ rẹ̀ pe, Wá, ẹ si jẹ ka ṣẹ keké, ki awa ki o le mọ̀ itori tani buburu yi ṣe wá sori wa. Bẹ̃ni nwọn ṣẹ keké, keké si mu Jona. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Sọ fun wa, awa bẹ̀ ọ, nitori ti tani buburu yi ṣe wá sori wa? kini iṣẹ rẹ? nibo ni iwọ si ti wá? orukọ ilu rẹ? orilẹ-ède wo ni iwọ si iṣe? On si wi fun wọn pe, Heberu li emi; mo si bẹ̀ru Oluwa, Ọlọrun ọrun, ti o dá okun ati iyangbẹ ilẹ. Nigbana ni awọn ọkunrin na bẹ̀ru gidigidi, nwọn si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi ṣe eyi? nitori awọn ọkunrin na mọ̀ pe o sá kuro niwaju Oluwa, nitori on ti sọ fun wọn.