Jon 1:7-10
Jon 1:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Olukuluku wọn si wi fun ẹgbẹ rẹ̀ pe, Wá, ẹ si jẹ ka ṣẹ keké, ki awa ki o le mọ̀ itori tani buburu yi ṣe wá sori wa. Bẹ̃ni nwọn ṣẹ keké, keké si mu Jona. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Sọ fun wa, awa bẹ̀ ọ, nitori ti tani buburu yi ṣe wá sori wa? kini iṣẹ rẹ? nibo ni iwọ si ti wá? orukọ ilu rẹ? orilẹ-ède wo ni iwọ si iṣe? On si wi fun wọn pe, Heberu li emi; mo si bẹ̀ru Oluwa, Ọlọrun ọrun, ti o dá okun ati iyangbẹ ilẹ. Nigbana ni awọn ọkunrin na bẹ̀ru gidigidi, nwọn si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi ṣe eyi? nitori awọn ọkunrin na mọ̀ pe o sá kuro niwaju Oluwa, nitori on ti sọ fun wọn.
Jon 1:7-10 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n bá dámọ̀ràn láàrin ara wọn, wọ́n ní “Ẹ jẹ́ kí á ṣẹ́ gègé, kí á lè mọ ẹni tí ó fà á, tí nǹkan burúkú yìí fi dé bá wa.” Wọ́n ṣẹ́ gègé, gègé bá mú Jona. Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa, nítorí ta ni nǹkan burúkú yìí fi dé bá wa? Kí ni iṣẹ́ rẹ? Níbo ni o ti wá? Níbo ni orílẹ̀-èdè rẹ? Inú ẹ̀yà wo ni o sì ti wá?” Ó bá dá wọn lóhùn pé: “Heberu ni mí, ẹ̀rù OLUWA ni ó bà mí, àní Ọlọrun ọ̀run, tí ó dá òkun ati ilẹ̀ gbígbẹ.” Ẹ̀rù ba àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ náà gidigidi, wọ́n sọ fún un pé, “Kí ni o dánwò yìí?” Nítorí wọ́n mọ̀ pé Jona ń sá kúrò níwájú OLUWA ni, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún wọn.
Jon 1:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ sọ fún ara wọn pé, “Wá, ẹ jẹ́ kí a sẹ́ kèké, kí àwa kí o le mọ̀ nítorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa.” Wọ́n ṣẹ́ kèké, kèké sì mú Jona. Nígbà náà ni wọn wí fún un pé, “Sọ fún wa, àwa bẹ̀ ọ́, nítorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa? Kí ni iṣẹ́ rẹ? Níbo ni ìwọ ti wá? Kí ni orúkọ ìlú rẹ? Ẹ̀yà orílẹ̀-èdè wo sì ni ìwọ sì í ṣe?” Òun sì dá wọn lóhùn pé, “Heberu ni èmi, mo sì bẹ̀rù OLúWA, Ọlọ́run ọ̀run ẹni tí ó dá Òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀.” Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù gidigidi, wọn sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣe èyí?” (Nítorí àwọn ọkùnrin náà mọ̀ pé ó ń sá kúrò ní iwájú OLúWA ni, nítorí òun ti sọ fun wọn bẹ́ẹ̀.)