JONA 1:7-10

JONA 1:7-10 YCE

Wọ́n bá dámọ̀ràn láàrin ara wọn, wọ́n ní “Ẹ jẹ́ kí á ṣẹ́ gègé, kí á lè mọ ẹni tí ó fà á, tí nǹkan burúkú yìí fi dé bá wa.” Wọ́n ṣẹ́ gègé, gègé bá mú Jona. Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa, nítorí ta ni nǹkan burúkú yìí fi dé bá wa? Kí ni iṣẹ́ rẹ? Níbo ni o ti wá? Níbo ni orílẹ̀-èdè rẹ? Inú ẹ̀yà wo ni o sì ti wá?” Ó bá dá wọn lóhùn pé: “Heberu ni mí, ẹ̀rù OLUWA ni ó bà mí, àní Ọlọrun ọ̀run, tí ó dá òkun ati ilẹ̀ gbígbẹ.” Ẹ̀rù ba àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ náà gidigidi, wọ́n sọ fún un pé, “Kí ni o dánwò yìí?” Nítorí wọ́n mọ̀ pé Jona ń sá kúrò níwájú OLUWA ni, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún wọn.