Job 40:1-5

Job 40:1-5 YBCV

OLUWA da Jobu lohùn si i pẹlu, o si wipe, Ẹniti mba Olodumare jà, yio ha kọ́ ọ li ẹkọ́? ẹniti mba Ọlọrun wi, jẹ ki o dahùn! Nigbana ni Jobu da Oluwa lohùn, o si wipe: Kiyesi i, ẹgbin li emi; ohùn kili emi o da? emi o fi ọwọ mi le ẹnu mi. Ẹ̃kan ni mo sọ̀rọ̀, ṣugbọn emi kì yio si tun sọ mọ, lẹ̃meji ni, emi kò si le iṣe e mọ́.