JOBU 40:1-5

JOBU 40:1-5 YCE

OLUWA tún sọ fún Jobu pé, “Ṣé ẹni tí ń bá eniyan rojọ́ lè bá Olodumare rojọ́? Kí ẹni tí ń bá Ọlọrun jiyàn dáhùn.” Nígbà náà ni Jobu dá OLUWA lóhùn, ó ní: “OLUWA, kí ni mo jámọ́, tí n óo fi dá ọ lóhùn? Nítorí náà, mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́. Mo ti sọ̀rọ̀ ju bí ó ti yẹ lọ, n kò sì ní sọ̀rọ̀ mọ́.”