Isa 59:10-11

Isa 59:10-11 YBCV

A nwá ogiri kiri bi afọju, awa si nwá ọ̀na bi ẹniti kò li oju: awa nkọsẹ lọsangangan bi ẹnipe loru, ni ibi ahoro, bi okú. Gbogbo wa mbu bi beari, awa si npohunrere bi oriri: awa wò ọ̀na fun idajọ, ṣugbọn kò si, fun igbala, ṣugbọn o jìna si wa.