AISAYA 59:10-11

AISAYA 59:10-11 YCE

À ń táràrà lára ògiri bí afọ́jú, à ń táràrà bí ẹni tí kò lójú. À ń kọsẹ̀ lọ́sàn-án gangan, bí ẹni tí ó jáde ní àfẹ̀mọ́júmọ́ a dàbí òkú láàrin àwọn alágbára. Gbogbo wa ń bú bí ẹranko beari, a sì ń ké igbe ẹ̀dùn bí àdàbà. À ń retí ìdájọ́ òdodo, ṣugbọn kò sí; à ń retí ìgbàlà, ṣugbọn ó jìnnà sí wa.