Isa 59:10-11
Isa 59:10-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
A nwá ogiri kiri bi afọju, awa si nwá ọ̀na bi ẹniti kò li oju: awa nkọsẹ lọsangangan bi ẹnipe loru, ni ibi ahoro, bi okú. Gbogbo wa mbu bi beari, awa si npohunrere bi oriri: awa wò ọ̀na fun idajọ, ṣugbọn kò si, fun igbala, ṣugbọn o jìna si wa.

Isa 59:10-11 Yoruba Bible (YCE)
À ń táràrà lára ògiri bí afọ́jú, à ń táràrà bí ẹni tí kò lójú. À ń kọsẹ̀ lọ́sàn-án gangan, bí ẹni tí ó jáde ní àfẹ̀mọ́júmọ́ a dàbí òkú láàrin àwọn alágbára. Gbogbo wa ń bú bí ẹranko beari, a sì ń ké igbe ẹ̀dùn bí àdàbà. À ń retí ìdájọ́ òdodo, ṣugbọn kò sí; à ń retí ìgbàlà, ṣugbọn ó jìnnà sí wa.
Isa 59:10-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gẹ́gẹ́ bí afọ́jú à ń táràrà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri tí a ń wá ọ̀nà wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí kò ní ojú. Ní ọ̀sán gangan ni à ń kọsẹ̀ bí ẹni pé alẹ́ ni; láàrín alágbára àwa dàbí òkú. Gbogbo wa là ń ké bí i beari; àwa pohùnréré ẹkún bí àdàbà A ń wá ìdájọ́ òdodo ṣùgbọ́n kò sí; à ń wọ́nà fún ìtúsílẹ̀, ṣùgbọ́n ó jìnnà réré.