Gẹn 26:17-35

Gẹn 26:17-35 YBCV

Isaaki si ṣí kuro nibẹ̀, o si pa agọ́ rẹ̀ ni afonifoji Gerari, o si joko nibẹ̀. Isaaki si tun wà kanga omi, ti nwọn ti wà li ọjọ́ Abrahamu, baba rẹ̀; nitori ti awọn ara Filistia ti dí wọn lẹhin ikú Abrahamu: o si pè orukọ wọn gẹgẹ bi orukọ ti baba rẹ̀ sọ wọn. Awọn ọmọ-ọdọ Isaaki si wàlẹ li afonifoji nì, nwọn si kàn kanga isun omi nibẹ̀. Awọn darandaran Gerari si mba awọn darandaran Isaaki jà, wipe, Ti wa li omi na: o si sọ orukọ kanga na ni Eseki; nitori ti nwọn bá a jà. Nwọn si tun wà kanga miran, nwọn si tun jà nitori eyi na pẹlu: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Sitna. O si ṣí kuro nibẹ̀, o si wà kanga miran: nwọn kò si jà nitori rẹ̀: o si pè orukọ rẹ̀ ni Rehoboti; o si wipe, Njẹ nigbayi li OLUWA tó fi àye fun wa, awa o si ma bisi i ni ilẹ yi. O si goke lati ibẹ̀ lọ si Beer-ṣeba. OLUWA si farahàn a li oru ọjọ́ na, o si wipe, Emi li Ọlọrun Abrahamu, baba rẹ: máṣe bẹ̀ru, nitori ti emi wà pẹlu rẹ, emi o si busi i fun ọ, emi o si mu irú-ọmọ rẹ rẹ̀, nitori Abrahamu ọmọ-ọdọ mi. O si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, o si kepè orukọ OLUWA, o si pa agọ́ rẹ̀ nibẹ̀: awọn ọmọ-ọdọ Isaaki si wà kanga kan nibẹ̀. Nigbana li Abimeleki tọ̀ ọ lati Gerari lọ, ati Ahusati, ọkan ninu awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ati Fikoli, olori ogun rẹ̀. Isaaki si bi wọn pe, Nitori kili ẹnyin ṣe tọ̀ mi wá, ẹnyin sa korira mi, ẹnyin si ti lé mi kuro lọdọ nyin? Nwọn si wipe, Awa ri i nitõtọ pe, OLUWA wà pẹlu rẹ: awa si wipe, Njẹ nisisiyi jẹ ki ibura ki o wà lãrin wa, ani lãrin tawa tirẹ, ki awa ki o si ba iwọ dá majẹmu; Pe iwọ ki yio ṣe wa ni ibi, bi awa kò si ti fọwọkàn ọ, ati bi awa kò si ti ṣe ọ ni nkan bikoṣe rere, ti awa si rán ọ jade li alafia: nisisiyi ẹni-ibukún OLUWA ni iwọ. O si sè àse fun wọn, nwọn si jẹ, nwọn si mu. Nwọn si dide ni kutukutu owurọ̀, nwọn si bura fun ara wọn: Isaaki si rán wọn pada lọ, nwọn si lọ kuro lọdọ rẹ̀ li alafia. O si ṣe li ọjọ́ kanna li awọn ọmọ-ọdọ Isaaki wá, nwọn si rò fun u niti kanga ti nwọn wà, nwọn si wi fun u pe, Awa kàn omi. O sọ orukọ rẹ̀ ni Ṣeba: nitorina li orukọ ilu na ṣe njẹ Beer-ṣeba titi di oni. Esau si di ẹni ogoji ọdún nigbati o mu Juditi li aya, ọmọbinrin Beeri, ara Hitti, ati Baṣemati, ọmọbinrin Eloni, ara Hitti: Ohun ti o ṣe ibinujẹ fun Isaaki ati fun Rebeka.