Gẹn 26:17-35

Gẹn 26:17-35 Bibeli Mimọ (YBCV)

Isaaki si ṣí kuro nibẹ̀, o si pa agọ́ rẹ̀ ni afonifoji Gerari, o si joko nibẹ̀. Isaaki si tun wà kanga omi, ti nwọn ti wà li ọjọ́ Abrahamu, baba rẹ̀; nitori ti awọn ara Filistia ti dí wọn lẹhin ikú Abrahamu: o si pè orukọ wọn gẹgẹ bi orukọ ti baba rẹ̀ sọ wọn. Awọn ọmọ-ọdọ Isaaki si wàlẹ li afonifoji nì, nwọn si kàn kanga isun omi nibẹ̀. Awọn darandaran Gerari si mba awọn darandaran Isaaki jà, wipe, Ti wa li omi na: o si sọ orukọ kanga na ni Eseki; nitori ti nwọn bá a jà. Nwọn si tun wà kanga miran, nwọn si tun jà nitori eyi na pẹlu: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Sitna. O si ṣí kuro nibẹ̀, o si wà kanga miran: nwọn kò si jà nitori rẹ̀: o si pè orukọ rẹ̀ ni Rehoboti; o si wipe, Njẹ nigbayi li OLUWA tó fi àye fun wa, awa o si ma bisi i ni ilẹ yi. O si goke lati ibẹ̀ lọ si Beer-ṣeba. OLUWA si farahàn a li oru ọjọ́ na, o si wipe, Emi li Ọlọrun Abrahamu, baba rẹ: máṣe bẹ̀ru, nitori ti emi wà pẹlu rẹ, emi o si busi i fun ọ, emi o si mu irú-ọmọ rẹ rẹ̀, nitori Abrahamu ọmọ-ọdọ mi. O si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, o si kepè orukọ OLUWA, o si pa agọ́ rẹ̀ nibẹ̀: awọn ọmọ-ọdọ Isaaki si wà kanga kan nibẹ̀. Nigbana li Abimeleki tọ̀ ọ lati Gerari lọ, ati Ahusati, ọkan ninu awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ati Fikoli, olori ogun rẹ̀. Isaaki si bi wọn pe, Nitori kili ẹnyin ṣe tọ̀ mi wá, ẹnyin sa korira mi, ẹnyin si ti lé mi kuro lọdọ nyin? Nwọn si wipe, Awa ri i nitõtọ pe, OLUWA wà pẹlu rẹ: awa si wipe, Njẹ nisisiyi jẹ ki ibura ki o wà lãrin wa, ani lãrin tawa tirẹ, ki awa ki o si ba iwọ dá majẹmu; Pe iwọ ki yio ṣe wa ni ibi, bi awa kò si ti fọwọkàn ọ, ati bi awa kò si ti ṣe ọ ni nkan bikoṣe rere, ti awa si rán ọ jade li alafia: nisisiyi ẹni-ibukún OLUWA ni iwọ. O si sè àse fun wọn, nwọn si jẹ, nwọn si mu. Nwọn si dide ni kutukutu owurọ̀, nwọn si bura fun ara wọn: Isaaki si rán wọn pada lọ, nwọn si lọ kuro lọdọ rẹ̀ li alafia. O si ṣe li ọjọ́ kanna li awọn ọmọ-ọdọ Isaaki wá, nwọn si rò fun u niti kanga ti nwọn wà, nwọn si wi fun u pe, Awa kàn omi. O sọ orukọ rẹ̀ ni Ṣeba: nitorina li orukọ ilu na ṣe njẹ Beer-ṣeba titi di oni. Esau si di ẹni ogoji ọdún nigbati o mu Juditi li aya, ọmọbinrin Beeri, ara Hitti, ati Baṣemati, ọmọbinrin Eloni, ara Hitti: Ohun ti o ṣe ibinujẹ fun Isaaki ati fun Rebeka.

Gẹn 26:17-35 Yoruba Bible (YCE)

Isaaki kúrò níbẹ̀, ó lọ tẹ̀dó sí àfonífojì Gerari. Isaaki tún àwọn kànga tí wọ́n ti gbẹ́ nígbà ayé Abrahamu baba rẹ̀ gbẹ́, nítorí pé, kò pẹ́ lẹ́yìn tí Abrahamu kú ni àwọn ará Filistia ti dí wọn. Ó sì sọ àwọn kànga náà ní orúkọ tí baba rẹ̀ sọ wọ́n. Ṣugbọn nígbà tí àwọn iranṣẹ Isaaki gbẹ́ kànga kan ní àfonífojì náà tí wọ́n sì kan omi, àwọn darandaran ará Gerari bá àwọn tí wọn ń da ẹran Isaaki jà, wọ́n wí pé, “Àwa ni a ni omi kànga yìí.” Nítorí náà ni Isaaki ṣe sọ kànga náà ní Eseki, nítorí pé wọ́n bá a jà nítorí rẹ̀. Àwọn iranṣẹ Isaaki tún gbẹ́ kànga mìíràn, òun náà tún dìjà, nítorí náà Isaaki sọ ọ́ ní Sitina. Ó kúrò níbẹ̀, ó lọ gbẹ́ kànga mìíràn, ẹnikẹ́ni kò sì bá a jà sí i, ó bá sọ ọ́ ní Rehoboti, ó wí pé, “Nisinsinyii Ọlọrun ti pèsè ààyè fún wa, a óo sì pọ̀ sí i ní ilẹ̀ yìí.” Láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí Beeriṣeba. OLUWA sì fara hàn án ní òru ọjọ́ tí ó rin ìrìn àjò náà, ó ní, “Èmi ni Ọlọrun Abrahamu, baba rẹ, má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo bukun ọ, n óo sì sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ nítorí ti Abrahamu iranṣẹ mi.” Ó bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó sì sin OLUWA. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì gbẹ́ kànga kan sibẹ. Abimeleki lọ sọ́dọ̀ Isaaki láti Gerari, òun ati Ahusati, olùdámọ̀ràn rẹ̀, ati Fikoli olórí ogun rẹ̀. Isaaki bá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ tún ń wá lọ́dọ̀ mi, nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ kórìíra mi tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ lé mi kúrò lọ́dọ̀ yín?” Wọ́n dáhùn pé, “A rí i dájú pé OLUWA wà pẹlu rẹ, ni a bá rò pé, ó yẹ kí àdéhùn wà láàrin wa, kí á sì bá ọ dá majẹmu, pé o kò ní pa wá lára, gẹ́gẹ́ bí àwa náà kò ti ṣe ọ́ níbi, àfi ire, tí a sì sìn ọ́ kúrò lọ́dọ̀ wa ní alaafia.” Isaaki bá se àsè fún wọn, wọ́n jẹ, wọ́n mu. Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, wọ́n ṣe ìbúra láàrin ara wọn, Isaaki bá sìn wọ́n sọ́nà, wọ́n sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ní alaafia. Ní ọjọ́ náà gan-an ni àwọn iranṣẹ rẹ̀ wá sọ fún un pé àwọn kan omi ninu kànga kan tí àwọn gbẹ́. Ó sọ kànga náà ní Ṣeba. Ìdí nìyí tí orúkọ ìlú náà fi ń jẹ́ Beeriṣeba títí di òní yìí. Nígbà tí Esau di ẹni ogoji ọdún, ó fẹ́ Juditi, ọmọ Beeri, ará Hiti ati Basemati, ọmọ Eloni, ará Hiti. Àwọn obinrin mejeeji yìí han Isaaki ati Rebeka léèmọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ayé sú wọn.

Gẹn 26:17-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Isaaki sì ṣí kúrò níbẹ̀, ó sì pàgọ́ sí Àfonífojì Gerari ó sì ń gbé ibẹ̀. Isaaki sì ṣe àtúngbẹ́ àwọn kànga tí Abrahamu baba rẹ̀ ti gbẹ́ nígbà ayé rẹ̀, èyí tí àwọn Filistini ti dí lẹ́yìn ikú Abrahamu baba rẹ̀, ó sì fún wọn lórúkọ tí baba rẹ̀ ti sọ wọ́n tẹ́lẹ̀. Àwọn ìránṣẹ́ Isaaki sì gbẹ́ kànga ní àfonífojì náà, wọ́n kan ìsun omi níbẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn darandaran Gerari ń bá àwọn darandaran Isaaki jà sí kànga náà pé àwọn ni àwọn ni í. Nítorí náà ni ó fi pe orúkọ kànga náà ní Eseki, nítorí pé wọ́n bá a jà sí kànga náà. Àwọn ìránṣẹ́ Isaaki tún gbẹ́ kànga mìíràn, wọ́n sì tún jà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Sitna (kànga àtakò). Ó sì tún kúrò níbẹ̀, ó sì gbẹ́ kànga mìíràn, wọn kò sì jásí èyí rárá, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Rehoboti, ó wí pé, “Nísinsin yìí, OLúWA ti fi ààyè gbà wá, a ó sì gbilẹ̀ si ní ilẹ̀ náà.” Láti ibẹ̀, ó kúrò lọ sí Beerṣeba Ní òru ọjọ́ tí ó dé ibẹ̀, OLúWA sì fi ara hàn án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu baba rẹ: Má ṣe bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì bùsi fún ọ, èmi yóò sì sọ iye ìran rẹ di púpọ̀, nítorí Abrahamu ìránṣẹ́ mi.” Isaaki sì kọ́ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì pe orúkọ OLúWA. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ sì gbẹ́ kànga kan níbẹ̀. Nígbà náà ni Abimeleki tọ̀ ọ́ wá láti Gerari, àti Ahussati, olùdámọ̀ràn rẹ̀ àti Fikoli, olórí ogun rẹ̀. Isaaki sì bi wọ́n léèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin tọ̀ mí wá, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin kórìíra mi tí ẹ sì lé mi jáde kúrò lọ́dọ̀ yín?” Wọ́n dáhùn pé, “A rí i dájú pé OLúWA wà pẹ̀lú rẹ, nítorí náà ni a fi rò ó wí pé, ó yẹ kí májẹ̀mú kí o wà láàrín àwa àti ìwọ. Jẹ́ kí a ṣe àdéhùn pé ìwọ kì yóò ṣe wá ní ibi, bí àwa pẹ̀lú kò ti ṣe ọ́ ní aburú, tí a sì ń ṣe ọ́ dáradára, tí a sì rán ọ jáde ní àlàáfíà láìṣe ọ́ ní ibi, kíyèsi OLúWA sì ti bùkún fún ọ.” Isaaki sì ṣe àsè fún wọn, wọn sì jẹ, wọ́n sì mu. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì wọn búra fún ara wọn. Isaaki sì rán wọn lọ, wọ́n sì lọ ní àlàáfíà. Ní ọjọ́ náà gan an ni àwọn ìránṣẹ́ Isaaki wá sọ fún un pé àwọn ti kan omi ní kànga kan tí àwọn gbẹ́. Ó sì pe orúkọ kànga náà ní Ṣiba (kànga májẹ̀mú), títí di òní olónìí, orúkọ ìlú náà ni Beerṣeba. Nígbà tí Esau pé ọmọ ogójì ọdún (40) ó fẹ́ ọmọbìnrin kan tí a ń pè ní Juditi, ọmọ Beeri, ará Hiti, ó sì tún fẹ́ Basemati, ọmọ Eloni ará Hiti. Fífẹ́ tí a fẹ́ àwọn obìnrin wọ̀nyí jẹ́ ìbànújẹ́ fún Isaaki àti Rebeka.