Isaaki kúrò níbẹ̀, ó lọ tẹ̀dó sí àfonífojì Gerari. Isaaki tún àwọn kànga tí wọ́n ti gbẹ́ nígbà ayé Abrahamu baba rẹ̀ gbẹ́, nítorí pé, kò pẹ́ lẹ́yìn tí Abrahamu kú ni àwọn ará Filistia ti dí wọn. Ó sì sọ àwọn kànga náà ní orúkọ tí baba rẹ̀ sọ wọ́n.
Ṣugbọn nígbà tí àwọn iranṣẹ Isaaki gbẹ́ kànga kan ní àfonífojì náà tí wọ́n sì kan omi, àwọn darandaran ará Gerari bá àwọn tí wọn ń da ẹran Isaaki jà, wọ́n wí pé, “Àwa ni a ni omi kànga yìí.” Nítorí náà ni Isaaki ṣe sọ kànga náà ní Eseki, nítorí pé wọ́n bá a jà nítorí rẹ̀.
Àwọn iranṣẹ Isaaki tún gbẹ́ kànga mìíràn, òun náà tún dìjà, nítorí náà Isaaki sọ ọ́ ní Sitina. Ó kúrò níbẹ̀, ó lọ gbẹ́ kànga mìíràn, ẹnikẹ́ni kò sì bá a jà sí i, ó bá sọ ọ́ ní Rehoboti, ó wí pé, “Nisinsinyii Ọlọrun ti pèsè ààyè fún wa, a óo sì pọ̀ sí i ní ilẹ̀ yìí.”
Láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí Beeriṣeba. OLUWA sì fara hàn án ní òru ọjọ́ tí ó rin ìrìn àjò náà, ó ní, “Èmi ni Ọlọrun Abrahamu, baba rẹ, má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo bukun ọ, n óo sì sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ nítorí ti Abrahamu iranṣẹ mi.” Ó bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó sì sin OLUWA. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì gbẹ́ kànga kan sibẹ.
Abimeleki lọ sọ́dọ̀ Isaaki láti Gerari, òun ati Ahusati, olùdámọ̀ràn rẹ̀, ati Fikoli olórí ogun rẹ̀. Isaaki bá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ tún ń wá lọ́dọ̀ mi, nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ kórìíra mi tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ lé mi kúrò lọ́dọ̀ yín?”
Wọ́n dáhùn pé, “A rí i dájú pé OLUWA wà pẹlu rẹ, ni a bá rò pé, ó yẹ kí àdéhùn wà láàrin wa, kí á sì bá ọ dá majẹmu, pé o kò ní pa wá lára, gẹ́gẹ́ bí àwa náà kò ti ṣe ọ́ níbi, àfi ire, tí a sì sìn ọ́ kúrò lọ́dọ̀ wa ní alaafia.” Isaaki bá se àsè fún wọn, wọ́n jẹ, wọ́n mu. Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, wọ́n ṣe ìbúra láàrin ara wọn, Isaaki bá sìn wọ́n sọ́nà, wọ́n sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ní alaafia.
Ní ọjọ́ náà gan-an ni àwọn iranṣẹ rẹ̀ wá sọ fún un pé àwọn kan omi ninu kànga kan tí àwọn gbẹ́. Ó sọ kànga náà ní Ṣeba. Ìdí nìyí tí orúkọ ìlú náà fi ń jẹ́ Beeriṣeba títí di òní yìí.
Nígbà tí Esau di ẹni ogoji ọdún, ó fẹ́ Juditi, ọmọ Beeri, ará Hiti ati Basemati, ọmọ Eloni, ará Hiti. Àwọn obinrin mejeeji yìí han Isaaki ati Rebeka léèmọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ayé sú wọn.