Gal 1:11-17

Gal 1:11-17 YBCV

Ṣugbọn, ará, mo fẹ ki ẹ mọ̀ pe ihinrere ti mo ti wasu kì iṣe nipa ti enia. Nitori kì iṣe lọwọ enia ni mo ti gbà a, bẹ̃li a kò fi kọ́ mi, ṣugbọn nipa ifihan Jesu Kristi. Nitori ẹnyin ti gburó ìwa-aiye mi nigba atijọ ninu ìsin awọn Ju, bi mo ti ṣe inunibini si ijọ enia Ọlọrun rekọja ãlà, ti mo si bà a jẹ: Mo si ta ọpọlọpọ awọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ ninu isin awọn Ju larin awọn ara ilu mi, mo si ni itara lọpọlọpọ si ofin atọwọdọwọ awọn baba mi. Ṣugbọn nigbati o wù Ọlọrun, ẹniti o yà mi sọtọ lati inu iya mi wá, ti o si pè mi nipa ore-ọfẹ rẹ̀, Lati fi Ọmọ rẹ̀ hàn ninu mi, ki emi le mã wasu rẹ̀ larin awọn Keferi; lojukanna emi kò bá ara ati ẹ̀jẹ gbìmọ pọ̀: Bẹ̃ni emi kò gòke lọ si Jerusalemu tọ̀ awọn ti iṣe Aposteli ṣaju mi; ṣugbọn mo lọ si Arabia, mo si tún pada wá si Damasku.