Gal 1

1
Ìkíni
1PAULU, Aposteli (ki iṣe lati ọdọ enia wá, tabi nipa enia, ṣugbọn nipa Jesu Kristi, ati Ọlọrun Baba, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú),
2Ati gbogbo awọn arakunrin ti o wà pẹlu mi, si awọn ijọ Galatia:
3Ore-ọfẹ si nyin ati alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Jesu Kristi Oluwa wa,
4Ẹniti o fi on tikalarẹ̀ fun ẹ̀ṣẹ wa, ki o le gbà wa kuro ninu aiye buburu isisiyi, gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun ati Baba wa:
5Ẹniti ogo wà fun lai ati lailai. Amin.
Kò Sí Ìyìn Rere Mìíràn
6Ẹnu yà mi nitoriti ẹ tete kuro lọdọ ẹniti o pè nyin sinu ore-ọfẹ Kristi, si ihinrere miran:
7Eyiti kì iṣe omiran; bi o tilẹ ṣe pe awọn kan wà ti nyọ nyin lẹnu, ti nwọn si nfẹ yi ihinrere Kristi pada.
8Ṣugbọn bi o ṣe awa ni, tabi angẹli kan lati ọrun wá, li o ba wasu ihinrere miran fun nyin ju eyiti a ti wasu fun nyin lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu.
9Bi awa ti wi ṣaju, bẹ̃ni mo si tún wi nisisiyi pe, Bi ẹnikan ba wasu ihinrere miran fun nyin jù eyiti ẹnyin ti gbà lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu.
10Njẹ nisisiyi enia ni emi nyi lọkàn pada tabi Ọlọrun? tabi enia ni emi nfẹ lati wù? nitoripe bi emi ba si nwù enia, emi kì yio le ṣe iranṣẹ Kristi.
Bí Paulu ti Ṣe Di Aposteli
11Ṣugbọn, ará, mo fẹ ki ẹ mọ̀ pe ihinrere ti mo ti wasu kì iṣe nipa ti enia.
12Nitori kì iṣe lọwọ enia ni mo ti gbà a, bẹ̃li a kò fi kọ́ mi, ṣugbọn nipa ifihan Jesu Kristi.
13Nitori ẹnyin ti gburó ìwa-aiye mi nigba atijọ ninu ìsin awọn Ju, bi mo ti ṣe inunibini si ijọ enia Ọlọrun rekọja ãlà, ti mo si bà a jẹ:
14Mo si ta ọpọlọpọ awọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ ninu isin awọn Ju larin awọn ara ilu mi, mo si ni itara lọpọlọpọ si ofin atọwọdọwọ awọn baba mi.
15Ṣugbọn nigbati o wù Ọlọrun, ẹniti o yà mi sọtọ lati inu iya mi wá, ti o si pè mi nipa ore-ọfẹ rẹ̀,
16Lati fi Ọmọ rẹ̀ hàn ninu mi, ki emi le mã wasu rẹ̀ larin awọn Keferi; lojukanna emi kò bá ara ati ẹ̀jẹ gbìmọ pọ̀:
17Bẹ̃ni emi kò gòke lọ si Jerusalemu tọ̀ awọn ti iṣe Aposteli ṣaju mi; ṣugbọn mo lọ si Arabia, mo si tún pada wá si Damasku.
18Lẹhin ọdún mẹta, nigbana ni mo gòke lọ si Jerusalemu lati lọ kí Peteru, mo si gbé ọdọ rẹ̀ ni ijọ mẹdogun.
19Ṣugbọn emi kò ri ẹlomiran ninu awọn Aposteli miran, bikoṣe Jakọbu arakunrin Oluwa.
20Nkan ti emi nkọ̀we si nyin yi, kiyesi i, niwaju Ọlọrun emi kò ṣeke.
21Lẹhin na mo si wá si ẹkùn Siria ati ti Kilikia;
22Mo sì jẹ ẹniti a kò mọ̀ li oju fun awọn ijọ ti o wà ninu Kristi ni Judea:
23Ṣugbọn kìki nwọn ti gbọ́ pe, Ẹniti o ti nṣe inunibini si wa rí, si nwasu igbagbọ́ na nisisiyi, ti o ti mbajẹ nigbakan rí.
24Nwọn si nyin Ọlọrun logo nitori mi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Gal 1: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa