GALATIA 1:11-17

GALATIA 1:11-17 YCE

Ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìyìn rere tí mò ń waasu kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ eniyan. Kì í ṣe ọwọ́ eniyan ni mo ti gbà á, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe eniyan ni ó kọ́ mi. Jesu Kristi ni ó fihàn mí. Nítorí ẹ ti gbúròó ìwà mi látijọ́ nígbà tí mo wà ninu ẹ̀sìn ti Juu, pé mò ń fìtínà ìjọ Ọlọrun ju bí ó ti yẹ lọ. Mo sa gbogbo ipá mi láti pa á run. Ninu ẹ̀sìn Juu, mo ta ọpọlọpọ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi ninu orílẹ̀-èdè mi yọ. Mo ní ìtara rékọjá ààlà ninu àṣà ìbílẹ̀ àwọn baba-ńlá mi. Ṣugbọn nígbà tí ó wu Ọlọrun, tí ó ti yà mí sọ́tọ̀ láti inú ìyá mi, ó fi oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ pè mí, láti fi Ọmọ rẹ̀ hàn ninu mi, kí n lè máa waasu ìyìn rere rẹ̀ láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Nígbà tí ó pè mí, n kò bá ẹnikẹ́ni gbèrò, n kò gòkè lọ sí Jerusalẹmu sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́ aposteli ṣiwaju mi, ṣugbọn mo lọ sí ilẹ̀ Arabia, láti ibẹ̀ ni mo tún ti pada sí Damasku.