GALATIA 1

1
Ìkíni
1Èmi Paulu, kì í ṣe eniyan ni ó pè mí láti jẹ́ aposteli, n kò sì ti ọ̀dọ̀ eniyan gba ìpè, Jesu Kristi ati Ọlọrun Baba, tí ó jí Jesu dìde, ni ó pè mí. 2Èmi ati gbogbo arakunrin tí ó wà lọ́dọ̀ mi ni à ń kọ ìwé yìí sí àwọn ìjọ Galatia.
3Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia Ọlọrun, Baba wa, wà pẹlu yín ati ti Oluwa Jesu Kristi, 4ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ ayé wa burúkú yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun Baba wa, 5ẹni tí ògo yẹ fún lae ati laelae. Amin.
Kò Sí Ìyìn Rere Mìíràn
6Ẹnu yà mí pé ẹ ti kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín nípa oore-ọ̀fẹ́ Kristi, ẹ ti yára yipada sí ìyìn rere mìíràn. 7Kò sí ìyìn rere mìíràn ju pé àwọn kan wà tí wọn ń yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n fẹ́ yí ìyìn rere Kristi pada. 8Ṣugbọn bí àwa fúnra wa tabi angẹli láti ọ̀run bá waasu ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí a ti waasu fun yín, kí olúwarẹ̀ di ẹni ègbé. 9Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, mo tún ń wí nisinsinyii pé bí ẹnikẹ́ni bá waasu ìyìn rere mìíràn fun yín, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ gbà, kí olúwarẹ̀ di ẹni ègbé.
10Ṣé ojurere eniyan ni mò ń wá nisinsinyii, tabi ti Ọlọrun? Àbí ohun tí ó wu eniyan ni mo fẹ́ máa ṣe? Bí ó bá jẹ́ pé ohun tí ó wu eniyan ni mò ń ṣe sibẹ, èmi kì í ṣe iranṣẹ Kristi.
Bí Paulu ti Ṣe Di Aposteli
11Ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìyìn rere tí mò ń waasu kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ eniyan. 12Kì í ṣe ọwọ́ eniyan ni mo ti gbà á, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe eniyan ni ó kọ́ mi. Jesu Kristi ni ó fihàn mí.
13Nítorí ẹ ti gbúròó ìwà mi látijọ́ nígbà tí mo wà ninu ẹ̀sìn ti Juu, pé mò ń fìtínà ìjọ Ọlọrun ju bí ó ti yẹ lọ. Mo sa gbogbo ipá mi láti pa á run. #A. Apo 8:3; 22:4-5; 26:9-11 14Ninu ẹ̀sìn Juu, mo ta ọpọlọpọ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi ninu orílẹ̀-èdè mi yọ. Mo ní ìtara rékọjá ààlà ninu àṣà ìbílẹ̀ àwọn baba-ńlá mi. #A. Apo 22:3
15Ṣugbọn nígbà tí ó wu Ọlọrun, tí ó ti yà mí sọ́tọ̀ láti inú ìyá mi, ó fi oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ pè mí, 16láti fi Ọmọ rẹ̀ hàn ninu mi, kí n lè máa waasu ìyìn rere rẹ̀ láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Nígbà tí ó pè mí, n kò bá ẹnikẹ́ni gbèrò, #A. Apo 9:3-6; 22:6-10; 26:13-18 17n kò gòkè lọ sí Jerusalẹmu sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́ aposteli ṣiwaju mi, ṣugbọn mo lọ sí ilẹ̀ Arabia, láti ibẹ̀ ni mo tún ti pada sí Damasku. 18Lẹ́yìn ọdún mẹta ni mo tó gòkè lọ sí Jerusalẹmu láti lọ rí Peteru, mo sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹẹdogun. #A. Apo 9:26-30 19Kò tún sí ọ̀kan ninu àwọn aposteli yòókù tí mo rí àfi Jakọbu arakunrin Oluwa.
20Mo fi Ọlọrun jẹ́rìí pé kò sí irọ́ ninu ohun tí mò ń kọ si yín yìí!
21Lẹ́yìn náà mo lọ sí agbègbè Siria ati ti Silisia. 22Àwọn ìjọ Kristi tí ó wà ní Judia kò mọ̀ mí sójú. 23Ṣugbọn wọ́n ń gbọ́ pé, “Ẹni tí ó ti ń fìtínà wa tẹ́lẹ̀ rí ti ń waasu ìyìn rere igbagbọ tí ó fẹ́ parun nígbà kan rí.” 24Wọ́n bá ń yin Ọlọrun lógo nítorí mi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

GALATIA 1: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀