GALATIA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ti ń waasu ìròyìn Ayọ̀ rẹ̀ káàkiri, iye àwọn tí kì í ṣe Juu ṣugbọn tí wọ́n gba Jesu gbọ́ bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i. Àríyànjiyàn bẹ́ sílẹ̀ pé bóyá ọ̀ranyàn ni pé kí eniyan tẹ̀lé òfin Mose kí ó tó lè jẹ́ onigbagbọ tòótọ́. Paulu ní tirẹ̀ ti sọ pé kì í ṣe dandan, àtipé ẹyọ nǹkankan ṣoṣo tí ó jẹ́ ọ̀ranyàn pé kí eniyan ní, kí ó tó lè ní ìyè ninu Kristi ni igbagbọ. Ó ní igbagbọ yìí nìkan ni ó lè sọ eniyan di olódodo níwájú Ọlọrun. Galatia jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ìpínlẹ̀ ìjọba Romu. Àwọn kan wá sáàrin àwọn ìjọ tí ó wà ní agbègbè Galatia yìí, tí wọn ń tako Paulu. Wọ́n ń wí pé dandan ni pé kí eniyan pa òfin Mose mọ́, kí Ọlọrun tó lè kà á sí olódodo.
Ìdí tí Paulu fi kọ ìwé tí ó kọ sí àwọn ará Galatia yìí ni láti mú kí àwọn tí wọn ń ṣì lọ́nà wọnyi mọ igbagbọ òtítọ́ ati irú ìṣesí tí ó yẹ onigbagbọ tòótọ́. Ohun tí Paulu fi bẹ̀rẹ̀ ni àlàyé lórí ìdí abájọ tí òun fi ní ẹ̀tọ́ láti jẹ́ aposteli Jesu Kristi. Ó tẹnumọ́ ọn pé Ọlọrun ló pe òun láti jẹ́ aposteli, kì í ṣe eniyan, ati pé àwọn tí kì í ṣe Juu ni Oluwa kanlẹ̀ rán òun sí. Lẹ́yìn náà ó ṣe àlàyé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pé igbagbọ nìkan ni ó lè sọ eniyan di olódodo níwájú Ọlọrun. Ninu àwọn orí bíi mélòó kan tí ó parí ìwé yìí, Paulu fihàn pé igbagbọ ninu Kristi ni okùnfà ìfẹ́ òtítọ́, tíí ṣe orísun gbogbo ìwà ati ìṣe onigbagbọ.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-10
Àṣẹ Paulu gẹ́gẹ́ bí Aposteli 1:11–2:21
Ìyìn rere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun 3:1–4:31
Òmìnira ati iṣẹ́ onigbagbọ 5:1–6:10
Ọ̀rọ̀ ìparí 6:11-18

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

GALATIA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀