II. Sam 7
7
Iṣẹ́ tí Natani jẹ́ fún Dafidi
(I. Kro 17:1-15)
1O si ṣe, nigbati ọba si joko ni ile rẹ̀, ti Oluwa si fun u ni isimi yika kiri kuro lọwọ gbogbo awọn ọta rẹ̀.
2Ọba si wi fun Natani woli pe, Sa wõ, emi ngbe inu ile ti a fi kedari kọ, ṣugbọn apoti-ẹri Ọlọrun ngbe inu ibi ti a fi aṣọ ke.
3Natani si wi fun ọba pe, Lọ, ki o si ṣe gbogbo eyi ti o wà li ọkàn rẹ, nitoripe Oluwa wà pẹlu rẹ.
4O si ṣe li oru na, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Natani wá, pe,
5Lọ, sọ fun iranṣẹ mi, fun Dafidi, pe, Bayi li Oluwa wi, iwọ o ha kọ ile fun mi ti emi o gbe?
6Nitoripe, emi ko iti gbe inu ile kan lati ọjọ ti emi ti mu awọn ọmọ Israeli goke ti ilẹ Egipti wá, titi di oni yi, ṣugbọn emi ti nrin ninu agọ, ati ninu agberin.
7Ni ibi gbogbo ti emi ti nrin larin gbogbo awọn ọmọ Israeli, emi ko ti iba ọkan ninu ẹya Israeli, ti emi pa aṣẹ fun lati ma bọ awọn enia mi ani Israeli sọ̀rọ pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi kedari kọ ile fun mi?
8Njẹ, nitorina, bayi ni iwọ o si wi fun iranṣẹ mi ani Dafidi pe, Bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, emi ti mu iwọ kuro lati inu agbo agutan wá, lati má mã tẹle awọn agutan, mo si fi ọ jẹ olori awọn enia mi, ani Israeli.
9Emi si wà pẹlu rẹ nibikibi ti iwọ nlọ, emi sa ke gbogbo awọn ọta rẹ kuro niwaju rẹ, emi si ti sọ orukọ rẹ di nla, gẹgẹ bi orukọ awọn enia nla ti o wà li aiye.
10Emi o si yàn ibi kan fun awọn enia mi, ani Israeli, emi o si gbìn wọn, nwọn o si ma joko ni ibujoko ti wọn, nwọn kì yio si ṣipo pada mọ; awọn ọmọ enia buburu kì yio si pọn wọn loju mọ, bi igba atijọ.
11Ati gẹgẹ bi akoko igba ti emi ti fi aṣẹ fun awọn onidajọ lori awọn enia mi, ani Israeli, emi fi isimi fun ọ lọwọ gbogbo awọn ọta rẹ. Oluwa si wi fun ọ pe, Oluwa yio kọ ile kan fun ọ.
12Nigbati ọjọ rẹ ba pe, ti iwọ o si sùn pẹlu awọn baba rẹ, emi o si gbe iru-ọmọ rẹ leke lẹhin rẹ, eyi ti o ti inu rẹ jade wá, emi o si fi idi ijọba rẹ kalẹ.
13On o si kọ ile fun orukọ mi, emi o si fi idi itẹ ijọba rẹ̀ kalẹ lailai.
14Emi o ma ṣe baba fun u, on o si ma jẹ ọmọ mi. Bi on ba dẹṣẹ, emi o si fi ọpá enia nà a, ati inà awọn ọmọ enia.
15Ṣugbọn ãnu mi kì yio yipada kuro lọdọ rẹ̀, gẹgẹ bi emi ti mu u kuro lọdọ Saulu, ti emi ti mu kuro niwaju rẹ.
16A o si fi idile rẹ ati ijọba rẹ mulẹ niwaju rẹ titi lai: a o si fi idi itẹ rẹ mulẹ titi lai.
17Gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi, ati gẹgẹ bi gbogbo iran yi, bẹ̃ni Natani si sọ fun Dafidi.
Adura Ọpẹ́ tí Dafidi Gbà
(I. Kro 17:16-27)
18Dafidi ọba si wọle lọ, o si duro niwaju Oluwa, o si wipe, Oluwa Ọlọrun, tali emi, ati ki si ni idile mi, ti iwọ fi mu mi di isisiyi?
19Nkan kekere li eyi sa jasi li oju rẹ, Oluwa Ọlọrun; iwọ si sọ ti idile iranṣẹ rẹ pẹlu ni ti akoko ti o jina. Eyi ha ṣe ìwa enia bi, Oluwa Ọlọrun?
20Kini Dafidi iba si ma wi si i fun ọ? Iwọ, Oluwa Ọlọrun mọ̀ iranṣẹ rẹ.
21Nitori ọ̀rọ rẹ, ati gẹgẹ bi ifẹ ọkàn rẹ, ni iwọ ṣe gbogbo nkan nla wọnyi, ki iranṣẹ rẹ ki o le mọ̀.
22Iwọ si tobi, Oluwa Ọlọrun: kò si si ẹniti o dabi rẹ, kò si si Ọlọrun kan lẹhin rẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti awa fi eti wa gbọ́.
23Orilẹ-ède kan wo li o si mbẹ li aiye ti o dabi awọn enia rẹ, ani Israeli, awọn ti Ọlọrun lọ ràpada lati sọ wọn di enia rẹ̀, ati lati sọ wọn li orukọ, ati lati ṣe nkan nla fun nyin, ati nkan iyanu fun ilẹ rẹ, niwaju awọn enia rẹ, ti iwọ ti ràpada fun ara rẹ lati Egipti wá, ani awọn orilẹ-ède ati awọn oriṣa wọn.
24Iwọ si fi idi awọn enia rẹ, ani Israeli, kalẹ fun ara rẹ lati sọ wọn di enia rẹ titi lai: iwọ Oluwa si wa di Ọlọrun fun wọn.
25Njẹ, Oluwa Ọlọrun, jẹ ki ọ̀rọ na ti iwọ sọ niti iranṣẹ rẹ, ati niti idile rẹ̀, ki o duro titi lai, ki o si ṣe bi iwọ ti wi.
26Jẹ ki orukọ rẹ ki o ga titi lai, pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li Ọlọrun lori Israeli: si jẹ ki a fi idile Dafidi iranṣẹ rẹ mulẹ niwaju rẹ.
27Nitoripe iwọ, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli ti sọ li eti iranṣẹ rẹ, pe, emi o ṣe idile kan fun ọ: nitorina ni iranṣẹ rẹ si ṣe ni i li ọkàn rẹ̀ lati gbadura yi si ọ.
28Njẹ, Oluwa Ọlọrun, iwọ li Ọlọrun na, ọrọ rẹ wọnni yio si jasi otitọ, iwọ si jẹ'jẹ nkan rere yi fun iranṣẹ rẹ:
29Njẹ, jẹ ki o wù ọ lati bukún idile iranṣẹ rẹ, ki o wà titi lai niwaju rẹ: nitori iwọ, Oluwa Ọlọrun, li o ti sọ ọ: si jẹ ki ibukún ki o wà ni idile iranṣẹ rẹ titi lai, nipasẹ ibukún rẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Sam 7: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.