II. Sam 8

8
Àwọn Ogun tí Dafidi jà ní àjàṣẹ́gun
(I. Kro 18:1-17)
1O SI ṣe, lẹhin eyi, Dafidi si kọlu awọn Filistini, o si tẹri wọn ba: Dafidi si gbà Metegamma lọwọ awọn Filistini.
2O si kọlu Moabu, a si fi okùn tita kan diwọ̀n wọn, o si da wọn bu'lẹ; o si ṣe oṣuwọn okun meji ni iye awọn ti on o pa, ati ẹkún oṣuwọn okùn kan ni iye awọn ti yio dá si. Awọn ara Moabu si nsìn Dafidi, nwọn a si ma mu ẹbùn wá.
3Dafidi si kọlu Hadadeseri ọmọ Rehobu, ọba Soba, bi on si ti nlọ lati gbà ilẹ rẹ̀ pada ti o gbè odo Eufrate.
4Dafidi si gbà ẹgbẹrun kẹkẹ lọwọ rẹ̀, ati ẹ̃dẹgbẹrin ẹlẹṣin, ati ẹgbãwa awọn ẹlẹsẹ: Dafidi si ja gbogbo ẹṣin kẹkẹ́ wọn wọnni ni pátì, ṣugbọn o da ọgọrun kẹkẹ́ si ninu wọn.
5Nigbati awọn ara Siria ti Damasku si wá lati ran Hadadeseri ọba Soba lọwọ, Dafidi si pa ẹgbãmọkanla enia ninu awọn ara Siria.
6Dafidi si fi awọn ologun si Siria ti Damasku: awọn ara Siria si wa sìn Dafidi, nwọn a si ma mu ẹbùn wá. Oluwa si pa Dafidi mọ nibikibi ti o nlọ.
7Dafidi si gbà aṣà wura ti o wà lara awọn iranṣẹ Hadadeseri, o si ko wọn wá si Jerusalemu.
8Lati Beta, ati lati Berotai, awọn ilú Hadadeseri, ni Dafidi ọba si ko ọ̀pọlọpọ idẹ wá.
9Nigbati Toi ọba Hamati si gbọ́ pe Dafidi ti pa gbogbo ogun Hadadeseri,
10Toi si ran Joramu ọmọ rẹ̀ si Dafidi ọba, lati ki i, ati lati sure fun u, nitoripe o ti ba Hadadeseri jagun, o si ti pa a: nitoriti Hadadeseri sa ti ba Toi jagun. Joramu si ni ohun elo fadaka, ati ohun elo wura, ati ohun elo idẹ li ọwọ́ rẹ̀:
11Dafidi ọba si fi wọn fun Oluwa, pẹlu fadaka, ati wura ti o ti yà si mimọ́, eyi ti o ti gbà lọwọ awọn orilẹ-ède ti o ti ṣẹgun;
12Lọwọ Siria ati lọwọ Moabu, ati lọwọ awọn ọmọ Ammoni, ati lọwọ awọn Filistini, ati lọwọ Amaleki, ati ninu ikogun Hadadeseri ọmọ Rehobu ọba Soba.
13Dafidi si ni asiki gidigidi nigbati o pada wá ile lati ibi pipa awọn ara Siria li afonifoji iyọ̀, awọn ti o pa jẹ ẹgbãsan enia.
14O si fi awọn ologun si Edomu; ati ni gbogbo Edomu yika li on si fi ologun si, gbogbo awọn ti o wà ni Edomu si wá sin Dafidi. Oluwa si pa Dafidi mọ nibikibi ti o nlọ.
15Dafidi si jọba lori gbogbo Israeli; Dafidi si ṣe idajọ ati otitọ fun awọn enia rẹ̀.
16Joabu ọmọ Seruia li o si nṣe olori ogun; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi si nṣe akọwe.
17Ati Sadoku ọmọ Ahitubu, ati Ahimeleki ọmọ Abiatari, li awọn alufa; Seruia a si ma ṣe akọwe.
18Benaiah ọmọ Jehoiada li o si nṣe olori awọn Kereti, ati awọn Peleti; awọn ọmọ Dafidi si jẹ alaṣẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Sam 8: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀