II. Sam 6

6
Wọ́n Gbé Àpótí Ẹ̀rí Wá sí Jerusalẹmu
(I. Kro 13:1-14; 15:25—16:6,43)
1DAFIDI si tun ko gbogbo awọn akọni ọkunrin ni Israeli jọ, nwọn si jẹ ẹgbã mẹ̃dogun.
2Dafidi si dide, o si lọ, ati gbogbo awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀, lati Baale ti Juda wá, lati mu apoti-ẹri Ọlọrun ti ibẹ wá, eyi ti a npè orukọ rẹ̀ ni orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun ti o joko lãrin awọn Kerubu.
3Nwọn si gbe apoti-ẹri Ọlọrun na gun kẹkẹ́ titun kan, nwọn si mu u lati ile Abinadabu wá, eyi ti o wà ni Gibea: Ussa ati Ahio, awọn ọmọ Abinadabu si ndà kẹkẹ́ titun na.
4Nwọn si mu u lati ile Abinadabu jade wá, ti o wà ni Gibea, pẹlu apoti-ẹri Ọlọrun; Ahio si nrìn niwaju apoti-ẹri na.
5Dafidi ati gbogbo ile Israeli si ṣire niwaju Oluwa lara gbogbo oniruru elò orin ti a fi igi arere ṣe, ati lara duru, ati lara psalteri, ati lara timbreli, ati lara korneti, ati lara aro.
6Nigbati nwọn si de ibi ipakà Nakoni, Ussa si nà ọwọ́ rẹ̀ si apoti-ẹri Ọlọrun, o si dì i mu, nitoriti malu kọsẹ.
7Ibinu Oluwa si ru si Ussa; Ọlọrun si pa a nibẹ nitori iṣiṣe rẹ̀; nibẹ li o si kú li ẹba apoti-ẹri Ọlọrun.
8Inu Dafidi si bajẹ nitoriti Oluwa ke Ussa kuro: o si pe orukọ ibẹ na ni Peresi-Ussa titi o fi di oni yi.
9Dafidi si bẹru Oluwa ni ijọ na, o si wipe, Apoti-ẹri Oluwa yio ti ṣe tọ̀ mi wá?
10Dafidi kò si fẹ mu apoti-ẹri Oluwa sọdọ rẹ̀ si ilu Dafidi: ṣugbọn Dafidi si mu u yà si ile Obedi-Edomu ara Gati.
11Apoti-ẹri Oluwa si gbe ni ile Obedi-Edomu ara Gati li oṣu mẹta: Oluwa si bukún fun Obedi-Edomu, ati gbogbo ile rẹ̀.
12A si rò fun Dafidi ọba, pe, Oluwa ti bukún fun ile Obedi-Edomu, ati gbogbo eyi ti iṣe tirẹ̀, nitori apoti-ẹri Ọlọrun. Dafidi si lọ, o si mu apoti-ẹri Ọlọrun na goke lati ile Obedi-Edomu wá si ilu Dafidi ton ti ayọ̀.
13O si ṣe, nigbati awọn enia ti o rù apoti-ẹri Oluwa ba si ṣi ẹsẹ mẹfa, on a si fi malu ati ẹran abọpa rubọ.
14Dafidi si fi gbogbo agbara rẹ̀ jó niwaju Oluwa; Dafidi si wọ̀ efodu ọgbọ̀.
15Bẹ̃ni Dafidi ati gbogbo ile Israeli si gbe apoti-ẹri Oluwa goke wá, ti awọn ti iho ayọ̀, ati pẹlu iro ipè.
16Bi apoti-ẹri Oluwa si ti wọ̀ ilu Dafidi wá; Mikali ọmọbinrin Saulu si wò lati oju ferese, o si ri Dafidi ọba nfò soke o si njo niwaju Oluwa; on si kẹgàn rẹ̀ li ọkàn rẹ̀.
17Nwọn si mu apoti-ẹri Oluwa na wá, nwọn si gbe e kalẹ sipò rẹ̀ larin agọ na ti Dafidi pa fun u: Dafidi si rubọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ niwaju Oluwa.
18Dafidi si pari iṣẹ ẹbọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ na, o si sure fun awọn enia na li orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun.
19O si pin fun gbogbo awọn enia na, ani fun gbogbo ọpọ enia Israeli, ati ọkunrin ati obinrin; fun olukuluku iṣu akara kan ati ẹkirí ẹran kan, ati akara didun kan. Gbogbo awọn enia na si tuka lọ, olukuluku si ile rẹ̀.
20Dafidi si yipada lati sure fun awọn ara ile rẹ̀, Mikali ọmọbinrin Saulu si jade lati wá pade Dafidi, o si wipe, Bi o ti ṣe ohun ogo to loni fun ọba Israeli, ti o bọ ara rẹ̀ silẹ loni loju awọn iranṣẹbinrin awọn iranṣẹ rẹ̀, gẹgẹ bi ọkan ninu awọn enia asan iti bọra rẹ̀ silẹ!
21Dafidi si wi fun Mikali pe, Niwaju Oluwa ni, ẹniti o yàn mi fẹ jù baba rẹ lọ, ati ju gbogbo idile rẹ̀ lọ, lati fi emi ṣe olori awọn enia Oluwa, ani lori Israeli, emi o si ṣire niwaju Oluwa.
22Emi o si tun rẹ̀ ara mi silẹ jù bẹ̃ lọ, emi o si ṣe alainiyìn loju ara mi, ati loju awọn iranṣẹbinrin wọnni ti iwọ wi, lọdọ wọn na li emi o si li ogo.
23Mikali ọmọbinrin Saulu kò si bi ọmọ, titi o fi di ọjọ ikú rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Sam 6: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀