II. Sam 5

5
Dafidi di Ọba Israẹli ati ti Juda
(I. Kro 11:1-9; 14:1-7)
1GBOGBO ẹya Israeli si tọ̀ Dafidi wá ni Hebroni, nwọn si wipe, Wõ, egungun rẹ ati ẹran ara rẹ li awa iṣe.
2Ati nigba atijọ, nigbati Saulu fi jọba lori wa, iwọ ni ẹniti ima ko Israeli jade, iwọ ni si ma mu wọn bọ̀ wá ile: Oluwa si wi fun ọ pe, Iwọ o bọ́ Israeli awọn enia mi, iwọ o si jẹ olori fun Israeli.
3Gbogbo agba Israeli si tọ ọba wá ni Hebroni, Dafidi ọba si ba wọn ṣe adehun kan ni Hebroni, niwaju Oluwa: nwọn si fi ororo yan Dafidi li ọba Israeli.
4Dafidi si jẹ ẹni ọgbọn ọdun nigbati o jọba; on si jọba li ogoji ọdun.
5O jọba ni Hebroni li ọdun meje on oṣu mẹfa lori Juda: o si jọba ni Jerusalemu li ọdun mẹtalelọgbọn lori gbogbo Israeli ati Juda.
6Ati ọba ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ Jerusalemu sọdọ awọn ara Jebusi, awọn enia ilẹ na: awọn ti o si ti wi fun Dafidi pe, Bikoṣepe iwọ ba mu awọn afọju ati awọn arọ kuro, iwọ ki yio wọ ìhin wá: nwọn si wipe, Dafidi ki yio lè wá sihin.
7Ṣugbọn Dafidi si fi agbara gbà ilu odi Sioni: eyi na ni iṣe ilu Dafidi.
8Dafidi si sọ lọjọ na pe, Ẹnikẹni ti yio kọlu awọn ara Jebusi, jẹ ki o gbà oju àgbàrá, ki o si kọlu awọn arọ ati awọn afọju ti ọkàn Dafidi korira. Nitorina ni nwọn ṣe wipe, Afọju ati arọ wà nibẹ, kì yio le wọle.
9Dafidi si joko ni ile awọn ọmọ-ogun ti o ni odi, a si npè e ni ilu Dafidi. Dafidi mọ ògiri yi i ka lati Millo wá, o si kọ ile ninu rẹ̀.
10Dafidi si npọ̀ si i, Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun si wà pẹlu rẹ̀.
11Hiramu ọba Tire si rán awọn iranṣẹ si Dafidi, ati igi kedari, ati awọn gbẹnàgbẹnà, ati awọn ti ngbẹ́ okuta ogiri: nwọn si kọ́ ile kan fun Dafidi.
12Dafidi si kiyesi i pe, Oluwa ti fi idi on mulẹ lati jọba lori Israeli, ati pe, o gbe ijọba rẹ̀ ga nitori Israeli awọn enia rẹ̀.
13Dafidi si tun mu awọn alè ati aya si i lati Jerusalemu wá, lẹhin igbati o ti Hebroni bọ̀: nwọn si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin fun Dafidi.
14Eyi si ni orukọ awọn ti a bi fun u ni Jerusalemu, Ṣammua ati Ṣobabu, ati Natani, ati Solomoni,
15Ati Ibehari, ati Eliṣua, ati Nefegi, ati Jafia,
16Ati Eliṣama, ati Eliada, ati Elifaleti,
Dafidi Ṣẹgun Àwọn Ará Filistia
(I. Kro 14:8-17)
17Ṣugbọn nigbati awọn Filistini gbọ́ pe, nwọn ti fi Dafidi jọba lori Israeli, gbogbo awọn Filistini si goke wá lati wa Dafidi; Dafidi si gbọ́, o si sọkalẹ lọ si ilu odi.
18Awọn Filistini si wá, nwọn si tẹ́ ara wọn li afonifoji Refaimu.
19Dafidi si bere lọdọ Oluwa, pe, Ki emi ki o goke tọ̀ awọn Filistini bi? iwọ o fi wọn le mi lọwọ bi? Oluwa si wi fun Dafidi pe, Goke lọ: nitoripe, dajudaju emi o fi awọn Filistini le ọ lọwọ.
20Dafidi si de Baal-perasimu, Dafidi si pa wọn nibẹ, o si wipe, Oluwa ti ya lù awọn ọtá mi niwaju mi, gẹgẹ bi omi iti ya. Nitorina li on ṣe pe orukọ ibẹ na ni Baal-perasimu.
21Nwọn si fi oriṣa wọn silẹ nibẹ, Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si ko wọn.
22Awọn Filistini si tún goke wá, nwọn si tàn ara wọn kalẹ ni afonifoji Refaimu.
23Dafidi si bere lọdọ Oluwa, on si wipe, Máṣe goke lọ; ṣugbọn bù wọn lẹhin, ki o si kọlu wọn niwaju awọn igi Baka.
24Yìo si ṣe, nigbati iwọ ba gbọ́ iro ẹsẹ lori awọn igi Baka na, nigbana ni iwọ o si yara, nitoripe nigbana li Oluwa yio jade lọ niwaju rẹ, lati kọlu ogun awọn Filistini.
25Dafidi si ṣe bẹ̃, gẹgẹ bi Oluwa ti paṣẹ fun u; o si kọlu awọn Filistini lati Geba titi o fi de Gaseri.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Sam 5: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀