Gadi si tọ Dafidi wá li ọjọ na, o si wi fun u pe, Goke, tẹ́ pẹpẹ kan fun Oluwa nibi ipaka Arauna ara Jebusi. Gẹgẹ bi ọ̀rọ Gadi, Dafidi si goke lọ gẹgẹ bi Oluwa ti pa a li aṣẹ. Arauna si wò, o si ri ọba ati awọn iranṣẹ rẹ̀ mbọ̀ wá ọdọ rẹ̀: Arauna si jade, o si wolẹ niwaju ọba o si doju rẹ̀ bolẹ. Arauna si wipe, Nitori kili oluwa mi ọba ṣe tọ iranṣẹ rẹ̀ wá? Dafidi si dahùn pe, Lati rà ibi ipaka nì lọwọ rẹ, lati tẹ́ pẹpẹ kan fun Oluwa, ki arùn iparun ki o le da li ara awọn enia na. Arauna si wi fun Dafidi pe, Jẹ ki oluwa mi ọba ki o mu eyi ti o dara li oju rẹ̀, ki o si fi i rubọ: wõ, malu niyi lati fi ṣe ẹbọ sisun, ati ohun elo ipaka, ati ohun elo miran ti malu fun igi. Gbogbo nkan wọnyi ni Arauna fi fun ọba, bi ọba. Arauna si wi fun ọba pe, Ki Oluwa Ọlọrun rẹ ki o gbà ọrẹ rẹ. Ọba si wi fun Arauna pe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn emi o rà a ni iye kan lọwọ rẹ, bi o ti wù ki o ṣe; bẹ̃li emi kì yio fi eyiti emi kò nawo fun, rú ẹbọ sisun si Oluwa Ọlọrun mi. Dafidi si rà ibi ipaka na, ati awọn malũ na li ãdọta ṣekeli fadaka. Dafidi si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ si Oluwa, o si rú ẹbọ sisun ati ti ìlaja. Oluwa si gbọ́ ẹbẹ fun ilẹ na, arùn na si da kuro ni Ìsraeli.
Kà II. Sam 24
Feti si II. Sam 24
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Sam 24:18-25
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò