II. Sam 24:18-25

II. Sam 24:18-25 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ náà gan-an, Gadi tọ Dafidi lọ, ó sì wí fún un pé, “Lọ sí ibi ìpakà Arauna kí o sì tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA níbẹ̀.” Dafidi pa àṣẹ OLUWA mọ́, ó sì lọ sí ibi ìpakà Arauna, gẹ́gẹ́ bí Gadi ti sọ fún un. Nígbà tí Arauna wo ìsàlẹ̀, ó rí ọba ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọn ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó lọ pàdé rẹ̀, ó kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó bi í pé, “Ṣé kò sí, tí oluwa mi, ọba, fi wá sọ́dọ̀ èmi, iranṣẹ rẹ̀?” Dafidi dá a lóhùn pé, “Ilẹ̀ ìpakà rẹ ni mo fẹ́ rà, mo fẹ́ tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA, kí àjàkálẹ̀ àrùn yìí lè dáwọ́ dúró.” Arauna dá a lóhùn pé, “Máa mú un, kí o sì mú ohunkohun tí o bá fẹ́ fi rúbọ sí OLUWA. Akọ mààlúù nìwọ̀nyí, tí o lè fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Àwọn àjàgà wọn nìwọ̀nyí, ati àwọn igi ìpakà tí o lè lò fún igi ìdáná.” Arauna kó gbogbo rẹ̀ fún ọba, ó ní, “Kí OLUWA Ọlọrun rẹ gba ẹbọ náà.” Ṣugbọn ọba dá a lóhùn pé, “Rárá o, n óo san owó rẹ̀ fún ọ, nítorí pé ohunkohun tí kò bá ní ná mi lówó, n kò ní fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun mi.” Dafidi bá ra ibi ìpakà ati àwọn akọ mààlúù náà, ní aadọta ṣekeli owó fadaka. Ó kọ́ pẹpẹ kan sibẹ fún OLUWA, ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia. OLUWA gbọ́ adura rẹ̀ lórí ilẹ̀ náà, àjàkálẹ̀ àrùn náà sì dáwọ́ dúró ní ilẹ̀ Israẹli.

II. Sam 24:18-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Gadi sì tọ Dafidi wá ní ọjọ́ náà, ó sì wí fún un pé, “Gòkè, tẹ́ pẹpẹ kan fún OLúWA lórí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi.” Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Gadi, Dafidi sì gòkè lọ bí OLúWA ti pa á ní àṣẹ. Arauna sì wò, ó sì rí ọba àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ wá lọ́dọ̀ rẹ̀: Arauna sì jáde, ó sì wólẹ̀ níwájú ọba ó sì dojú rẹ̀ bolẹ̀. Arauna sì wí pé, “Nítorí kín ni olúwa mi ọba ṣe tọ ìránṣẹ́ rẹ̀ wá?” Dafidi sì dáhùn pé, “Láti ra ibi ìpakà rẹ lọ́wọ́ rẹ, láti tẹ́ pẹpẹ kan fún OLúWA, kí ààrùn ìparun lè dá lára àwọn ènìyàn náà.” Arauna sì wí fún Dafidi pé, “Jẹ́ kí olúwa mi ọba ó mú èyí tí ó dára lójú rẹ̀, kí o sì fi í rú ẹbọ: wò ó, màlúù nìyìí láti fi ṣe ẹbọ sísun, àti ohun èlò ìpakà, àti ohun èlò mìíràn ti màlúù fún igi. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni Arauna fi fún ọba, bí ọba. Arauna sì wí fún ọba pé, Kí OLúWA Ọlọ́run rẹ ó gba ọrẹ rẹ.” Ọba sì wí fún Arauna pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́; ṣùgbọ́n èmi ó rà á ní iye kan lọ́wọ́ rẹ, bí ó ti wù kí ó ṣe; bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi èyí tí èmi kò náwó fún, rú ẹbọ sísun sí OLúWA Ọlọ́run mi.” Dafidi sì ra ibi ìpakà náà, àti àwọn màlúù náà ní àádọ́ta ṣékélì fàdákà. Dafidi sì tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ sí OLúWA, ó sì rú ẹbọ sísun àti ti ìlàjà. OLúWA sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ fún ilẹ̀ náà, ààrùn náà sì dá kúrò ní Israẹli.