Ní ọjọ́ náà gan-an, Gadi tọ Dafidi lọ, ó sì wí fún un pé, “Lọ sí ibi ìpakà Arauna kí o sì tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA níbẹ̀.” Dafidi pa àṣẹ OLUWA mọ́, ó sì lọ sí ibi ìpakà Arauna, gẹ́gẹ́ bí Gadi ti sọ fún un. Nígbà tí Arauna wo ìsàlẹ̀, ó rí ọba ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọn ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó lọ pàdé rẹ̀, ó kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó bi í pé, “Ṣé kò sí, tí oluwa mi, ọba, fi wá sọ́dọ̀ èmi, iranṣẹ rẹ̀?”
Dafidi dá a lóhùn pé, “Ilẹ̀ ìpakà rẹ ni mo fẹ́ rà, mo fẹ́ tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA, kí àjàkálẹ̀ àrùn yìí lè dáwọ́ dúró.”
Arauna dá a lóhùn pé, “Máa mú un, kí o sì mú ohunkohun tí o bá fẹ́ fi rúbọ sí OLUWA. Akọ mààlúù nìwọ̀nyí, tí o lè fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Àwọn àjàgà wọn nìwọ̀nyí, ati àwọn igi ìpakà tí o lè lò fún igi ìdáná.” Arauna kó gbogbo rẹ̀ fún ọba, ó ní, “Kí OLUWA Ọlọrun rẹ gba ẹbọ náà.”
Ṣugbọn ọba dá a lóhùn pé, “Rárá o, n óo san owó rẹ̀ fún ọ, nítorí pé ohunkohun tí kò bá ní ná mi lówó, n kò ní fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun mi.” Dafidi bá ra ibi ìpakà ati àwọn akọ mààlúù náà, ní aadọta ṣekeli owó fadaka. Ó kọ́ pẹpẹ kan sibẹ fún OLUWA, ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia. OLUWA gbọ́ adura rẹ̀ lórí ilẹ̀ náà, àjàkálẹ̀ àrùn náà sì dáwọ́ dúró ní ilẹ̀ Israẹli.