I. Pet 3:8-11

I. Pet 3:8-11 YBCV

Lakotan, ki gbogbo nyin ṣe oninu kan, ẹ mã ba ará nyin kẹdun, ẹ ni ifẹ ará, ẹ mã ṣe ìyọnú, ẹ ni ẹmí irẹlẹ. Ẹ máṣe fi buburu san buburu, tabi fi ẽbú san ẽbú; ṣugbọn kàka bẹ̃, ẹ mã súre; nitori eyi li a pè nyin si, ki ẹnyin ki o le jogún ibukún. Nitori, ẹniti yio ba fẹ ìye, ti yio si ri ọjọ rere, ki o pa ahọn rẹ̀ mọ́ kuro ninu ibi, ati ète rẹ̀ kuro ni sisọ ọrọ ẹ̀tan: Ki o yà kuro ninu ibi, ki o si mã ṣe rere; ki o mã wá alafia, ki o si mã lepa rẹ̀.