I. Pet 3

3
Ọ̀rọ̀ fún Àwọn Ọkọ ati Aya
1BẸ̃ gẹgẹ, ẹnyin aya, ẹ mã tẹriba fun awọn ọkọ nyin; pe, bi ẹnikẹni bá tilẹ nṣe aigbọran si ọ̀rọ na, ki a lè jere wọn li aisọrọ nipa ìwa awọn aya wọn,
2Nigbati nwọn ba nwò ìwa rere ti on ti ẹ̀ru nyin:
3Ọṣọ́ ẹniti ki o má jẹ ọṣọ́ ode, ti irun didì, ati ti wura lilo, tabi ti aṣọ wiwọ̀;
4Ṣugbọn ki o jẹ ti ẹniti o farasin li ọkàn, ninu ọ̀ṣọ́ aidibajẹ ti ẹmí irẹlẹ ati ẹmí tutù, eyiti iṣe iyebiye niwaju Ọlọrun.
5Nitori bayi li awọn obinrin mimọ́ igbãni pẹlu, ti nwọn gbẹkẹle Ọlọrun, fi ṣe ara wọn li ọ̀ṣọ́, nwọn a mã tẹriba fun awọn ọkọ tiwọn.
6Gẹgẹ bi Sara ti gbọ́ ti Abrahamu, ti o npè e li oluwa: ọmọbinrin ẹniti ẹnyin iṣe, bi ẹnyin ba nṣe rere, ti ohunkohun kò si dẹruba nyìn.
7Bẹ̃ gẹgẹ ẹnyin ọkọ, ẹ mã fi oye bá awọn aya nyin gbé, ẹ mã fi ọla fun aya, bi ohun èlo ti kò lagbara, ati pẹlu bi ajumọ-jogun ore-ọfẹ ìye; ki adura nyin ki o má bã ni ìdena.
Ìjìyà Nítorí Òdodo
8Lakotan, ki gbogbo nyin ṣe oninu kan, ẹ mã ba ará nyin kẹdun, ẹ ni ifẹ ará, ẹ mã ṣe ìyọnú, ẹ ni ẹmí irẹlẹ.
9Ẹ máṣe fi buburu san buburu, tabi fi ẽbú san ẽbú; ṣugbọn kàka bẹ̃, ẹ mã súre; nitori eyi li a pè nyin si, ki ẹnyin ki o le jogún ibukún.
10Nitori, ẹniti yio ba fẹ ìye, ti yio si ri ọjọ rere, ki o pa ahọn rẹ̀ mọ́ kuro ninu ibi, ati ète rẹ̀ kuro ni sisọ ọrọ ẹ̀tan:
11Ki o yà kuro ninu ibi, ki o si mã ṣe rere; ki o mã wá alafia, ki o si mã lepa rẹ̀.
12Nitori oju Oluwa mbẹ lara awọn olododo, etí rẹ̀ si ṣí si ẹbẹ wọn: ṣugbọn oju Oluwa nwo awọn ti nṣe buburu.
13Tani yio si ṣe nyin ni ibi, bi ẹnyin ba jẹ onítara si ohun rere?
14Ṣugbọn bi ẹnyin ba jìya nitori ododo, alafia ni: ẹ máṣe bẹru wọn, ki ẹ má si ṣe kọminu;
15Ṣugbọn ẹ bọ̀wọ fun Kristi bi Oluwa lọkan nyin: ki ẹ si mura tan nigbagbogbo lati dá olukuluku lohùn ti mbere ireti ti o mbẹ ninu nyin, ṣugbọn pẹlu ọkàn tutù ati ìbẹru.
16Ki ẹ mã ni ẹri-ọkàn rere, bi nwọn ti nsọ̀rọ nyin ni ibi, ki oju ki o le ti awọn ti nkẹgan iwa rere nyin ninu Kristi.
17Nitori o san, bi o bá jẹ ifẹ Ọlọrun, ki ẹ jìya fun rere iṣe jù fun buburu iṣe lọ.
18Nitoriti Kristi pẹlu jìya lẹ̃kan nitori ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ fun awọn alaiṣõtọ, ki o le mu wa de ọdọ Ọlọrun, ẹniti a pa ninu ara, ṣugbọn ti a sọ di ãye ninu ẹmí:
19Ninu eyiti o lọ pẹlu, ti o si wãsu fun awọn ẹmí ninu tubu:
20Awọn ti o ṣe alaigbọran nigbakan, nigbati sũru Ọlọrun duro pẹ ni sã kan ni ọjọ Noa, nigbati nwọn fi nkàn ọkọ̀ ninu eyiti à gba ọkàn diẹ là nipa omi, eyini ni ẹni mẹjọ;
21Apẹrẹ eyiti ngbà nyin là nisisiyi pẹlu, ani baptismu, kì iṣe ìwẹ ẽri ti ara nù, bikoṣe idahùn ọkàn rere sipa Ọlọrun, nipa ajinde Jesu Kristi:
22Ẹniti o ti lọ si ọrun, ti o si mbẹ li ọwọ́ ọtún Ọlọrun; awọn angẹli, ati awọn ọlọlá, ati awọn alagbara si ntẹriba fun.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Pet 3: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa