Ní gbolohun kan, ẹ ní inú kan sí ara yín. Ẹ ni ojú àánú. Ẹ ní ìfẹ́ sí ara yín. Ẹ máa ṣoore. Ẹ ní ọkàn ìrẹ̀lẹ̀. Ẹ má fi burúkú gbẹ̀san burúkú, tabi kí ẹ fi àbùkù kan ẹni tí ó bá fi àbùkù kàn yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa sọ̀rọ̀ wọn ní rere ni. Irú ìwà tí a ní kí ẹ máa hù nìyí, kí ẹ lè jogún ibukun tí Ọlọrun ṣèlérí fun yín. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ẹni tí ó bá fẹ́ ìgbé-ayé tí ó wù ú, tí ó fẹ́ rí ọjọ́ tí ó dára, ó níláti kó ara rẹ̀ ni ìjánu pẹlu ọ̀rọ̀ burúkú sísọ, kí ó má fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. Ó níláti yipada kúrò ninu ìwà burúkú, kí ó máa hu ìwà rere. Ó níláti máa wá alaafia, kí ó sì máa lépa rẹ̀.
Kà PETERU KINNI 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: PETERU KINNI 3:8-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò