I. Kro 4:1-4

I. Kro 4:1-4 YBCV

AWỌN ọmọ Juda; Faresi, Hesroni, ati Karmi, ati Huri, ati Ṣobali. Reaiah ọmọ Ṣobali si bi Jahati; Jahati si bi Ahumai, ati Lahadi. Wọnyi ni idile awọn ara Sora. Awọn wọnyi li o ti ọdọ baba Etamu wá; Jesreeli ati Jisma, ati Jidbaṣi: orukọ arabinrin wọn si ni Selelponi: Ati Penueli ni baba Gedori, ati Eseri baba Huṣa. Wọnyi ni awọn ọmọ Huri, akọbi Efrata, baba Betlehemu.